Mínísítà fọ́rọ̀ ohun àmúsagbára Adebayo Adelabu ṣàlàyé ìdí tó fi kọ̀wé fipò sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Bayo Adelab/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Minisita fun ọrọ ohun amuṣagbara, Adebayo Adelabu, ti kọwe fipo silẹ lati le dupo gomina ipinlẹ Oyo.

Adelabu ṣalaye igbesẹ rẹ ninu iwe kan to fi ranṣẹ si Aarẹ Bola Tinubu lọjọ kejilelogun oṣu kẹrin yii.

Ọfiisi akọwe ijọba apapọ, Ṣẹnẹtọ George Akume, ni Adelabu ti lọ fi iwe naa ranṣẹ si Aarẹ Tinubu.

Adelabu ṣalaye ninu lẹta naa wi pe pẹlu idunnu ati ayọ loun fi kọwe fipo silẹ.

O wa dupẹ lọwọ aarẹ fun anfaani ti o fun un lati sin orilẹede Naijiria.

Adelabu ni oore ọfẹ nla loun ri gba lati ọdọ Tinubu lori bi o ṣe yan oun sipo mínísítà fun ọrọ ohun amuṣagbara.

Adelabu fikun ọrọ rẹ pe nnkan iwuri lo jẹ foun wi pe oun lanfaani lati kópa toun naa ninu idagbasoke Naijiria, papaa julọ nipasẹ akanṣe iṣẹ toun ti ṣe ni ẹka ohun amusagbara.

Eekan ẹgbẹ oṣelu APC naa ni oun kọwe fipo silẹ lati le lọ dupo gomina ipinlẹ Oyo.

O ni lati ọdun 2016 toun ti wa nipo igbakeji banki apapọ Naijiria, CBN ni oun ti n gbero lati jẹ gomina ipinlẹ Oyo.

Adelabu ni erongba oun yii lo jẹ koun kọwe fipo silẹ ni CBN lọdun 2018.

O ṣalaye siwaju ṣii pe oun kọwe fipo silẹ tori ofin Naijiria ko faye gba ki oṣiṣẹ ọba maa dupo òṣèlú.

Adelabu ni idi gan an niyi ti oun fi kọwe fipo silẹ gẹgẹ bi mínísítà ohun amuṣagbara.