Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì ṣo ohun tó pa Jesu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ti a ba yọwọ ọrọ ẹsin kuro, awọn eeyan kan naa gbagbọ pe ọkunrin kan wa ti wọn n pe ni Jesu, to ti gbe ori ilẹ aye yii ri ni nnkan bii ẹgbẹrun meji ọdun sẹyin, ni ilu ti a mọ si Israel bayii.

Ẹya Jew ni Jesu, o dari awọn to tẹle e, ṣugbọn iṣesi rẹ ko tẹ awọn alaṣẹ ilẹ Rome lọrun.

Fun idi eyi, wọn pada fiya jẹ ẹ, wọn mu un wọn si kan an mọgi gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe nigba naa.

Lẹyin iku Jesu, awọn olutẹle rẹ bẹrẹ si i kede ihinrere rẹ. Lẹyin iku rẹ ni ọrọ ẹsin ati ẹkọ nipa rẹ bẹrẹ.

Amọ ki ni Jesu ṣe fun awọn alaṣẹ Rome ti wọn fi korira rẹ, ti wọn si pada pa a nilana ijiya ati iṣekupani igba naa.

Itan sọ nipa bi wọn ṣe de e lade ẹgun, ti wọn fi ọ̀kọ̀ gun un, ti wọn kan iṣo mọ ọwọ ati ẹsẹ rẹ, ti wọn si kan mọ igi agbelebuu, igi oro ati igi itiju igbaani.

Ikede ijọba ọrun, idajọ ododo ti Jesu n ṣe ko tẹ ijọba aye lọrun

Onpitan ati Ọjọgbọn André Leonardo Chevitarese, ṣalaye pe opo mẹrin ni iyinrere Jesu da le lori, eyi to tako ijọba aye to wa ni Rome nigba naa.

" Nitori Jesu n lewaju ijọba tuntun, ijọba ọrun si ni, ti Baba.

Gẹgẹ bi opo mẹrin ti Jesu kede ṣe wa, idajọ ododo lati ode ọrun wa ni opo akọkọ. Jesu sọ pe ijọba mi jẹ ti otitọ, ti Kesari jẹ ai si idajọ ododo."

Opo keji ni pe gbogbo eeyan lo gbọdọ le jẹun dọgba, ko ma si irẹjẹ.

O tun kede alaafia to yẹ ko kari, pẹlu ijọba kan ti gbogbo eeyan yoo ni ipin ninu rẹ lai yọ ẹnikẹni silẹ"

Gbogbo eyi ko tẹ ijọba igba naa lọrun, wọn si bẹrẹ si i dọdẹ Jesu titi ti wọn fi mu un lọjọ to wọ Jerusalemu.

"Lọjọ Ajinde, ninu ilu to kun fun awọn Jew ti wọn n ṣe ẹsin ọtọọtọ, wọn ri I to n ba wọn ja ninu tẹmpili, awọn alaṣẹ si wo o pe asiko to daa ju lati mu un niyẹn."

Bẹẹ ni onpitan naa ṣalaye.

"Gbogbo awọn ajiyinrere ni wọn gba pe ọjọ Ẹti ni iku Jesu waye, lasiko isinmi Ajinde."

Giuseppe Ricciotti, Alufa ilẹ Italy ati onkọwe Vita di Gesù Cristo, sọ pe o ṣee ṣe ki ọjọ ti wọn kan Jesu mọ agbelebu jẹ ọjọ keje, oṣu Kẹrin 30 AD (April 7, 30 AD).

Ijiya ikẹyin fun Jesu

Ki wọn kan eeyan mọ agbelebu lo wọpọ ninu idajọ iku lasiko naa.

Wọn maa n dana sun awọn ẹlomi-in, wọn yoo si sọ awọn elomiran di oku nipa sinsin wọn laaye nibi ti wọn yoo ṣe wọn lọ́jọ̀ si.

"Kikan eeyan mọ agbelebuu jẹ ilana ijiya ẹṣẹ nla ti awọn Rome maa n fi jẹ ẹni to ba je ẹrú, atawọn ti ko ba ki n ṣe ọmọ ilu Rome lati 217 BC,"

Gerardo Ferrara lo ṣalaye bẹẹ.

"Ijiya to mu itiju wa ni, wọn ki I ṣe bẹẹ fun ọmọ ilu Rome.

Bawo ni ijiya lori agbelebuu ṣe ri?

Nigba ti ẹni ti wọn kan mọ agbelebuu ṣi wa laye, ti ẹmi rẹ ko ti I bọ tan lori igi naa, awọn ẹyẹ yoo maa ṣa a jẹ nibi to wa.

Lẹyin ọjọ mẹta si mẹrin, awọn ẹranko a jẹ oku ẹni naa bo ṣe n jẹra."

Chevitarese lo ṣalaye bẹẹ.

Ninu iwe 'Crucifixion of Jesus, Frederick Thomas Zugibe (1928-2013), Ọjọgbọn lati Yunifasiti Columbia, ṣalaye ohun to le ṣẹlẹ si ẹni ti wọn kan mọ agbelebuu to fi ku.

"Ninu itan, wọn ki i sin oku awọn ti wọn ba kan mọ agbelebuu, amọ ninu ẹsin igbagbọ, o han pe wọn sinku Jesu o si ji pada."

Ohun ti Sayẹnsi sọ pe o pa Jesu

Dokita Zugibe ninu alaye rẹ, sọ pe ohun ti akọsilẹ sọ ni pe apa ibi ti Jesu gbe lara agbelebuu naa wuwo ni iwọn mejilelogun (22kg).

Awon igun yoku rẹ si jẹ 80kg si 90kg.

Ko rọrun lati gbe e fun igba pipẹ. Ohun ti wọn gbagbọ ni pe Jesu gbe agbelebuu naa rin de kilomita mẹjọ ( 8km).

Nipa bi Jesu ṣe ku, Dokita Zugibe sọ pe awọn oluwadi gba pe wọn kan iṣo ti ìwọ̀n rẹ jẹ 12.5 mọ atẹlẹwọ rẹ.

Bi Jesu ṣe wa lori agbelebuu, wọn tun kan iṣo mọ ẹsẹ rẹ. Iso naa ni yoo ba awọn iṣan pataki jẹ, yoo si mu inira alailẹgbẹ wa.

"Bawo ni yoo ṣe pẹ to ki ẹni to n jẹ iru irora yii too ku? Niṣe ni wọn maa n ku pẹlu gìrì ti yoo gbe wọn.

"Eyi maa n jẹ ki iṣan ara daṣẹ silẹ, ẹni naa yoo si ku latari ai ri atẹgun mi sinu ati inira."

Cevitares lo ṣalaye bẹẹ.

Ferrara sọ pe idaṣẹsilẹ ọkan lo pa Jesu, latari ijiya ti wọn mu un la kọja.

Nipasẹ iwadii rẹ, Joukibe jábọ̀ pe nnkan mẹta ni igbagbọ wa ni nilana sayẹnsi pe o pa Jesu.

Awọn nnkan naa ni : Ai ri eemi mi sinu mọ latara inira (Asphyxiation), idaṣẹsilẹ ọkan (Heart attack) ati ai le kọja ẹjẹ sinu ara mọ (Hemorrhagic shock.)

Iwadii rẹ gba pe Jesu ku nitori ọkan rẹ to daṣẹ silẹ, nitori ẹjẹ rẹ to lọ silẹ lati ara ijiya to koju.

"O ṣee ṣe ki asiko ti Jesu fi jiya naa to wakati diẹ. O le ma to wakati meji, o si ṣee ṣe ko jẹ nitori ẹjẹ to ti padanu ki wọn too kan an mọgi."

Bẹẹ ni Ferrara sọ pe iwadii gbagbọ nilana Sayẹnsi.