Oníṣẹ̀ṣe bẹ́ ajá síwáju pẹpẹ ṣọ́ọ̀ṣì, lẹ́yìn táwọn pásítọ̀ wọ ojúbọ Osun Osogbo, aáwọ̀ ẹ̀sìn bẹ̀rẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Òwò ki I fun òwò lọrun ni owe Yoruba wi, bẹẹ ni kaluku lo ni ibi ti ofin ti faaye gba a lati ṣe ijọsin eyikeyi to ba wu u.

To ba wa di pe ẹnikan wọ ibi ti ki I ṣe tirẹ tabi ti ofin ko fi aaye gba a lati de, ohun to ṣẹlẹ nipinlẹ Osun yii lo ṣee ṣe ko waye.

Eyi ni ohun ti ọpọ eeyan n sọ lori ayelujara bayii, lori fidio kan to ṣafihan awọn pasitọ kan lojubọ oriṣa, ti wọn n sọ pe ki oriṣa naa ma gba ẹbọ mọ nipinlẹ Osun.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Ninu fidio kan to ṣafihan iṣẹlẹ yii loju opo Facebook, a ri awọn pasitọ kan lojubọ naa ti wọn wọ aṣọ adura (sutana).

Ọkunrin kan ninu awọn pasitọ naa n fi ọwọ kan awọn oriṣa to wa lojubọ naa, o n sọrọ to fi ajulọ Jesu Kristi han, o si n sọ pe agbara yẹpẹrẹ ni ti oriṣa.

Bakan naa ni pasitọ yii sọ pe ki oriṣa naa ma ṣe gba ẹbọ mọ, oun gbe gbogbo ẹbọ mi, awọn to ku rẹ si n ṣe ami bo ṣe n ṣe adura naa.

Awọn Oniṣẹṣe da a pada fun ṣọọṣi, wọn bẹ aja siwaju pẹpẹ

Lẹyin ti awọn pasitọ naa ṣe tiwọn tan, fidio yii tẹsiwaju lati ṣafihan ibi ti awọn Oniṣẹṣe naa ti wọ ṣọọṣi ti awọn pasitọ ti wa, lati gbẹsan.

Ninu ṣọọṣi ti awọn pasitọ naa jokoo si ni awọn Oniṣẹṣẹ wọ ti wọn si n beere lọwọ wọn pe ṣe awọn kọ ni wọn wa si idi Osun, amọ pasitọ kankan ko dahun

"Ogun laakaye ti ẹ n lulu le lori lo de yii."

Bẹẹ ni ẹnikan wi lara awọn Oniṣẹṣẹ naa.

Awon meji gbe aja dani, ẹni kan pa igo mọlẹ, wọn si gbe aja naa lọ sibi pẹpẹ ṣọọṣi, wọn gbe aago ṣọọṣi si abẹ rẹ, ẹnikan ni ki wọn bẹ aja naa lori, wọn si bẹ ẹ.

"Esu laalu okiri oko, iwọ ni wọn waa ba a o, a o tọ wọn. Ogun ye mo ye."

Eyi ati bẹẹ bẹẹ lọ ni awọn Oniṣẹṣe naa n wi ninu ṣọọṣi, wọn ni awọn gbe aja naa fun wọn, ki wọn maa jẹ e.

Ẹnikan tilẹ gbe oku aja naa le ọkan lara awọn to wọ aṣọ funfun ninu ṣọọṣi naa lori, ki oku aja naa to jabọ silẹ lara rẹ.

Orin ni obinrin kan lara awọn Oniṣẹṣe naa n kọ pe: 'Agbara Jesu da nibi ti Esu ti n jọba, ko si o, o ti wo ."

Awọn Oniṣẹṣe naa sọ pe bo ṣe n ri lara lawọn fẹ kawọn Oniṣọọṣi naa mọ, nitori awọn ni wọn kọkọ lọ sidi oriṣa baba awọn.

Wọn ni wọn o ki i bẹ́ si Oniṣẹṣe, ki wọn jiṣẹ fun awọn pasitọ wọn ti wọn ba de.

Bẹẹ ni fidio naa pari.

Latigba ti fidio ọhun ti jade sita ni kaluku ti n so ero ọkan rẹ le e lori, ọpọ eeyan lo si gba pe awọn pasitọ to wọ igbalẹ Osun naa lo tọ wahala.

Awọn Oniṣẹṣẹ kọwe ifisun si ọlọpaa

Ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe nipinlẹ Osun ti kọwe ifisun si olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, latari awọn pasitọ kan ti wọ ojubọ Oriṣa Osun Osogbo, ti wọn si ṣe awọn ohun to jẹ eewọ ninu ojubọ naa.

Ifisun ọhun lo waye lalẹ ọjọ Aje ọsẹ yii, lẹyin ti wọn ni awọn pasitọ naa ti ṣe ohun ti wọn fẹ ṣe lojubọ Osun.

Bo si tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa naa ti gbe igbesẹ alaafia lati yanju ọrọ yii, nipa biba awọn aṣoju igun mejeeji ṣepade, sibẹ, ọrọ naa ko ti I tan nilẹ.

BBC Yoruba yoo ma fi to yin leti bo ba ṣe n lọ.