April Fool's Day: Wo bí ọjọ́ ìmúniṣeré ṣe bẹ̀rẹ̀ lágbàáyé, àtàwọn ẹ̀tàn mánigbàgbé tàwọn èèyàn ti ṣe

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Gbogbo ọjọ akọkọ ninu oṣu Kẹrin ọdun ni ayajọ imuniṣere ti a mọ si April Fool's Day ni gbogbo agbaye.

Bo si tilẹ jẹ pe ọjọ naa ki i ṣe ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ, sibẹ, ẹgbẹgbẹrun eeyan lagbaaye lo máa n sayajọ ọjọ yii lati sọ nnkankan tabi omiran ti ki i ṣe ododo, ṣugbọn to jẹ imuni-nigan-an tabi imuniṣere lasan.

April Fool bawọn eeyan ṣe maa n pe e, jẹ ọjọ ẹtan ti yoo farajọ otitọ ki eeyan to pada mọ pe irọ ni.

Ni kukuru, ọjọ kin-in-ni oṣu Kẹrin ọdọọdun ti i se ayajọ ọjọ April Fool ni awọn eeyan ya sọtọ lati maa tan awọn ẹlomiran jẹ.

Amọ bawo ni ọjọ imuniṣere yii tiẹ ṣe bẹrẹ? Oriṣiriṣi itan lo rọ mọ eyi.

Awọn kan sọ pe Hilaria to jẹ ọjọ ọdun kan ni ilẹ Rome, ti wọn ma n ṣe ni ọjọ kẹẹẹdọgbọn osu kẹta lo bi ọjọ ẹ̀tàn yii.

Bakan naa ni awọn kan sọ pe lati inu iwe ti Geoffrey Chaucer kọ, to pe akọle rẹ ni 'Canterbuty Tales' ni ayajọ ọjọ itanjẹ naa ti bẹrẹ.

Itan bi April Fool se bẹrẹ:

Asa titan awọn ẹlomiran jẹ yii bẹrẹ lọdun 1582, lasiko ti Pope Gregory XIII se agbekalẹ Kalẹnda Gregorian to wa fun onka ọjọ ati osu.

Ninu kalẹnda ti wọn n lo bọ lati ẹyin wa, ọjọ Kin-in-ni osu Kẹrin ni ọdun tuntun bẹrẹ, ti wọn si maa n se ajọyọ rẹ.

Ṣugbọn nigba ti wọn paarọ kalẹnda naa, ti ọjọ akọkọ ninu ọdun jẹ Januari 1, awọn eeyan kan ṣi tun n tẹsiwaju lati maa se ajọyọ ọdun tuntun ni ọjọ kin-in-ni osu Kẹrin ọdọọdun.

Idi ree ti ọpọ eeyan se maa n fi awọn eeyan to n se ajọyọ ọdun tuntun loṣu Kẹrin naa se ẹlẹya, ti wọn si n pe wọn ni alaimọkan ati ẹlẹtan.

Ohun to fa a ti wọn fi n sọ pe April Fools ni wọn niyẹn, nitori ẹtan lasan ni ajọyọ ọjọ tuntun ti wọn n se loṣu Kẹrin naa.

Bi wọn ba fẹ fi awọn eeyan naa ṣe yẹyẹ nigba naa ni France, ohun ti wọn saba maa n ṣe fun wọn ni ki wọn ya aworan ẹja sinu iwe, ki wọn si gbe e si ẹyin awọn ọlọdun naa.

Itumọ eyi ni ẹja April, eyi ti wọn n pe ni "poisson d'avril", lede wọn.

Itumọ eyi ni ọmọ ẹja to rọrun lati mu lodo tabi ẹni to dẹrun lati tanjẹ.

Ẹwẹ, ọjọ ẹtan yii bẹrẹ nilẹ Britain ni Sẹnturi kejidinlogun, ọjọ meji ni wọn tilẹ ya sọtọ fun un ni Scotland.

Eto kan ti wọn n pe ni "Hunting the gowk" lo maa n ṣaaju, nibi ti wọn yoo ti ran awọn eeyan jade lati lọ wa ohun ti ko sọnu.

Ọjọ keji rẹ ni wọn n pe ni Ọjọ Tailie, nibi ti wọn yoo ti so ìrù mọ ẹnikan nidii, tabi ki wọn kọ 'ta mi nipaa' (Kick me) sinu iwe ki wọn si gbe e si ẹni naa lẹyin, ko maa gbe e kiri.

Ni ti ilẹ Rome to kari ju, ọdun Hilaria ni wọn so ọjọ yii mọ, itumọ Hilaria lede Latin si ni ayọ.

Ipari ọsu Kẹta ni awọn ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Cybele cult maa n ṣe e.

Awọn olukopa naa yoo wọ aṣọ ẹtan ti ẹnikẹni ko fi ni i da wọn mọ, wọn yoo si maa fi awọn eeyan ṣe yẹyẹ.

Ki ni pataki ayajọ April Fool?

Ọjọ Kin-in-ni osu kẹrin ti wọn maa n se ayajọ ọjọ ẹtan yii lo wa lati da apara ti ko pa ni lara.

Amọ nigba miran, awọn ẹtanjẹ mi-in maa n lagbara, eyi to le se ipalara fun awọn elomiran.

Ikilọ to wa fun ayajọ yii ni pe awọn eeyan gbọdọ sọra lati ma ṣe da apapra to le pa ẹlomiran lara, tabi to le koba ilera wọn.

Bakan naa ni wọn ko gbọdọ gbe iroyin irọ to le maa tan kalẹ jade.

Wo awọn itanjẹ tawọn eeyan ti se ni Ọjọ April Fool ri

Ọjọ April Fool ti ọdun 2019 ni ile isẹ iroyin kan fi lede pe agbabọọlu Super Eagles, Alex Iwobi ti kuro ni Arsenal lọ si Barcelona.

Bakan naa ni awọn eniyan kan ni Ilẹ Gẹẹsi lọdun 2019 sọ pe wọn ti wọgile bii Ilẹ Gẹẹsi se fẹ kuro ninu ajọ isọkan ilẹ Yuroopu ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti wọn si n beere pe ki awọn eeyan mu eleyii to ba jẹ April Fool ninu rẹ.

Oju opo imọ ẹrọ Google naa ko gbẹyin ninu itanjẹ Ọjọ April Fool.

Wọn fi lede ni 2019 pe awọn ti se ẹrọ ti yoo mu ki eeyan le ba ewe Tulip sọrọ, ti ewe naa yoo si ma a fun eeyan lesi.

Awọn imuniṣere miran to tun maa n waye ni ni:

*Ki ọmọbinrin to ṣi n lọ sile ẹkọ sọ fawọn obi ẹ pe oun ti loyun

* Ki ọkunrin tabi obinrin kede igbeyawo lori irọ.

* Ki wọn ni Dangote ti sọ owo epo di ẹẹdẹgbẹta naira

* Ki wọn ni awon oloju ipo ibaraẹnisọrọ ni ki ẹnikẹni ma sanwo ipe lonii April fool ati bẹẹ bẹẹ lọ.