You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ìgbésẹ̀ mẹ́sàn-án tí o máa gbé láti ṣe ìṣirò owó orí tí ò ń san fún ìjọba lọ́dọọdún
Ọpọ ọmọ Naijiria ti wọn n sanwo ori ni ko tii lanfaani lati ṣe iṣiro bi wọn ṣe n sanwo ori wọn gẹgẹ bi ijọba ṣe laa kalẹ titi di akoko yii.
Gẹgẹ bi ofin owo ori tuntun ọdun 2025 sẹ laa kalẹ, gbogbo ọmọ Naijiria to n san owo ori gbọdọ maa ṣe iṣiro owo ori ti wọn san lọdọọdun.
Alaga ajọ to n ṣagbatẹru ofin owo ori tuntun naa lọdun 2025 to ti di minisita abẹle fun eto iṣuna bayii, Taiwo Oyedele, ti sọ ṣaaju wi pe awọn ọmọ Naijiria gbọdọ ṣe iṣiro bi wọn ṣe san owo ori lọdun to kọja titi ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kẹta yii.
Oyedele ni atawọn oṣiṣẹ ati awọn to n gbawọn eeyan siṣẹ lo gbọdọ ṣe iṣiro owo ori ti wọn n san fun ijọba.
Ofin owo ori tuntun naa sọ pe awọn oṣiṣẹ ko gbọdọ sọ pe ojusẹ awọn ti tan lẹyin ti ijọba ba ti yọ owo ori ninu owo oṣu wọn.
Bayii ni o ṣe le ṣe iṣiro owo ori ti o n san fun ijọba:
1. Mọ isọri owo ori sisan ti o wa
Owo ori ọlọdanni ni irufẹ owo ori tawọn eeyan n san nipinlẹ ti wọn ti n ṣiṣẹ, yatọ si ipinlẹ abinibi wọn.
Fun awọn oṣiṣẹ to n gba owo oṣu, bi wọn ba ti sanwo fun wọn ni ijọba ti maa n yọ owo ori.
Amọ, awọn ipinlẹ maa n fẹ kawọn eeyan ṣe iṣiro bi wọn ṣe n sanwo ori lati le ṣe akọsilẹ owo ti wọn n san.
O si tun di dandan fawọn oniṣowo aladanni naa lati ṣe iṣiro owo ori wọn.
2. Gba nọmba idanimọ fun owo ori sisan rẹ
Awọn to ba fẹ ṣe iṣiro owo ori ti wọn n san gbọdọ gba nọmba idanimọ fun owo ori sisan.
Lori ayelujara ni o ti le ri kaadi owo ori sisan yii gba lori ikanni ajọ FIRS.
3. Mọ iye owo oṣu rẹ lọdun
Awọn to n sanwo ori gbọdọ ṣe iṣiro gbogbo owo ti wọn n san lọdun.
Awọn irufẹ owo bẹẹ ni:
Owo osu ati owo ajẹmọnu
Owo to n jade nibi okowo
Owo to n jade lati ibi iṣẹ aladaani
Ere lati ara owo ile gbigba
Owo lati ori ere
Owo ori lori owo to wọle lati ilẹ okeere
4. Ṣe iṣiro owo ori ti o n san
Iṣiro owo ori to n san gbọdọ ṣafihan gbogbo iye owo to n wọle fun ọ to fi mọ owo ti ijọba n yọ.
O le ṣe iṣiro owo ori rẹ lori ayelujara lori ikanni ajọ to n ri si owo ori sisan nipinlẹ kọọkan.
Awọn araalu ni lati tẹle ilana ipinlẹ wọn lori ọna ti wọn le gba ṣe iṣiro owo ori wọn.
Awọn ti wọn n ṣe iṣiro owo ori gbọdọ sọ nipa iṣẹ wọn ati atupalẹ gbogbo owo to n wọle fun wọn.
5. Gba iranwọ lori owo ori sisan
Labẹ ofin owo ori tuntun ọdun 2025, awọn to n sanwo ori le ri iranwọ gba lori owo ile ti wọn n san, owo iranwọ naa le to N500,000 tabi ida 20% owo ile ti wọn n san niwọn igba ti wọn ba le ṣafihan risiiti ti wọn fi sanwo.
6. Fi iṣiro owo ori rẹ ranṣẹ kiakia
Nnkan to wa ninu ofin owo ori tuntun 2025 ni pe gbogbo eeyan ni lati maa ṣe iṣiro owo ori wọn ko to di ọjọ kọkanlelọgbọn to jẹ ọjọ to kẹyin lati ṣe bẹẹ.
Awọn to ba kọ lati ṣe iṣiro owo ori wọn yoo san faini ati awọn owo mii.
Awọn alaṣẹ nipa owo ori gba araalu ni imọran lati tete ṣe iṣiro owo ori ki o ma baa nira fun wọn lati ṣe.
7. Awọn nnkan ti o nilo lati sẹ iṣiro owo ori rẹ
Awọn araalu to ba n sanwo ori ni lati ni awọn iwe yii lati ṣe iṣiro owo ori wọn ni irọrun.
Nọmba kaadi owo ori sisan
Kaadi idanimọ
Iwe to n ṣafihan owo to n wọle
Iwe banki lori owo to n wọle
Akọsilẹ ere okowo
Ẹri yiyọ owo ninu owo oṣu ri
Ẹri sisan owo ile
Risiiti owo ori sisan ti atẹyinwa
8. Lẹyin ti o ba ṣe iṣiro owo rẹ tan
Ti o ba ti ṣe iṣiro owo ori rẹ, ajọ to n ṣakoso owo ori nipinlẹ rẹ yoo kan si ọ wi pe o ti yege.
9. Idi ti o fi gbọdọ ṣe iṣiro owo ori rẹ
Ojuṣe rẹ ni lati ṣe iṣiro owo ori rẹ gẹgẹ bi ọmọ orilẹede Naijiria.
Yatọ fun pe o ko ni san faini, iṣiro owo ori siṣe ni o le fi gbaṣẹ lọdọ ijọba, ni anfaani si ẹyawo, ṣeto a ti gba fisa atawọn nnkan mii to ba nilo nini iwẹ ẹri owo ori.
Ijọba ipinlẹ Eko sun ṣiṣe iṣiro owo ori siwaju pẹu ọsẹ meji
Ẹwẹ, ajọ LIRS to n ṣakoso owo ori sisan nipinlẹ Eko ti sun gbedeke iṣe iṣiro owo ori sisan siwaju pẹlu ọsẹ meji.
Oni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kẹta yii lo yẹ ko jẹ ọjọ tom kẹyin lati ṣe iṣiro naa fun gbogbo eeyan.
Amọ, ọjọ kẹrinla oṣu Kẹrin to n bọ ni ijọba ipinlẹ Eko ti sun un siwaju da bayii.
Ajọ LIRS fọrọ yii lede ninu atẹjade ti Monsurat Amasa-Oyelude to jẹ adari ọrọ to n lọ fun ajọ ọhun fi sita.
Alaga ajọ LIRS, Ọmọwe yodele Subair, sọ ninu atẹjade naa wi pe igbesẹ yii waye lati fawọn eeyan lanfaani lati le pari iṣiro owo ori wọn.
Ọmọwe Subair ni awọn araalu ni lati maa mu sisẹ iṣiro owo ori wọn fun ijọba ni ọkunkundun.
O fikun ọrọ rẹ pe lori itakun ikanni LIRS nikan lawọn eeyan le ti ṣe iṣiro owo ori wọn.
Alaga ajọ LIRS rọ awọn araalu lati ṣe iṣiro owo ori wọn lori itakun TAXID ki wọn si lo kaadi idanimọ fun owo ori sisan wọn nibẹ.