You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
INEC ṣe àyípadà orúkọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ PDP sí ti igun Wike dìbò yàn lópin ọ̀sẹ̀
Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta, ọdún 2026 ni igun mínísítà fún ìlú Abuja, Nyesom Wike nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ṣe àpérò ẹgbẹ́ náà láti yan àwọn adarí ẹgbẹ́ tuntun.
Níbi àpérò náà tó wáyé ní pápá ìṣeré Moshood Abiola tó wà ní ìlú Abuja ni wọ́n ti kéde ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mọ́kàndínlógún tí yóò máa darí ẹgbẹ́ òṣèlú náà.
Gbogbo ìpínlẹ̀ káàkiri Nàìjíríà ni àwọn aṣojú PDP ti balẹ̀ síbi àpérò náà láti yan àwọn aláṣẹ tuntun tó máa ṣe àkóso ẹgbẹ́ òṣèlú náà fún ọdún mẹ́rin.
Àwọn aṣojú tí iye wọn tó 2,500 tó kópa níbi àpérò náà ló fẹnukò láti gbé àwọn aláṣẹ tuntun náà wọlé láì ṣe ètò ìdìbò kankan gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ náà ti ṣáájú kéde pé ìlànà fífi ẹnu kò lórí àwọn olùdíje ni àwón máa ṣe dípò ṣíṣe ètò ìdìbò.
Àpérò náà ṣàfihàn iyàpà tó ń wáyé nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP látàrí bí kò ṣe sí asojú láti àwọn ìpínlẹ̀ kan.
Lára ìpínlẹ̀ tí kò báwọn péjú síbi àpérò náà la ti rí ìpínlẹ̀ Edo, níbi tí ìjà abẹ́nú ti ń wáyé láàárín àwọn adarí ẹgbẹ́ náà ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún.
Ẹ ó rántí pé ní oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 ni igun tí gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ṣe ìpàdé àpérò ní ìlú Ibadan níbi tí wọ́n ti yan Kabiru Tanimu Turaki gẹ́gẹ́ bí alága ẹgbẹ́ PDP.
Àmọ́ ṣáájú àpérò náà ni ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja ti dájọ́ pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe ìpàdé ọ̀hún àti pé àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà kò gbọdọ̀ báwọn kópa níbẹ̀.
Lẹ́yìn náà ni ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tún da ẹjọ́ tí igun Makinde pè lórí ìpàdé náà nù tí wọ́n sì ní kí Turaki kò gbọdọ̀ pe ara rẹ̀ ní alága ẹgbẹ́ náà mọ́.
Àwọn wo ni ìgbìmọ̀ aláṣẹ PDP tuntun?
- Alága - Abdulrahman Mohammed
- Igbákejì alága (Gúúsù) - Aaron Chukwuemeka
- Igbákejì alága (Àríwá) - Yusufu Akirikwen (SAN);
- Akọ̀wé àpapọ̀ - Anyanwu Samuel
- Igbákejì akọ̀wé àpapọ̀ - Kolawale Olabisi
- Akápò - Odeyemei Oladiran
- Igbákejì akápò - Lado Marke
- Akọ̀wé owó - Eyim Henry
- Igbákejì akọ̀wé owó - Dr Grema Kyari
- Akọ̀wé akòsó ẹgbẹ́ - Umar Bature
- Igbákejì Akọ̀wé akòsó ẹgbẹ́ - Efere Augustine
- Agbẹnusọ ẹgbẹ́ - Jungudo Mohammed
- Igbákejì agbẹnusọ - Egwu Chidiebere
- Agbẹjọ́rò ẹgbẹ́ - Kamaldeen Ajibade (SAN)
- Igbákejì agbẹjọ́rò ẹgbẹ́ - Aloysius Uba
- Olùṣirò owó - Osuoha Donatus
- Igbákejì olùṣirò owó - Dr Adaba Yatu
- Olórí ọ̀dọ́ - Ibrahim Aboki
- Igbákejì olórí ọ̀dọ́ - Momoh Bashir.
- Olórí àwọn obìnrin - Ọ̀jọ̀gbọ́n Ogunshe Adedayo
- Igbákejì olórí àwọn obìnrin - Hauwa Shinge
Ìṣọ̀kan gbọdọ̀ wà ní PDP ṣáájú ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027 - Àwọn àgbà ẹgbẹ́ PDP
Pẹ̀lú gbogbo àwọn ìfaǹfà tó ń wáyé nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, àwọn èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú náà bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Abia tẹ́lẹ̀ rí Okezie Ikpeazu, alága tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn, Abdulrahman Mohammed, Nyesom Wike, Bukola Saraki, Sule Lamido ń pè fún ìpẹ̀tùsááwọ̀ láàárín àwọn tó ń fapá jánú nínú ẹgbẹ́ náà.
Wọ́n ní ó pọn dandan láti wà ní ìṣọ̀kan, kí àwọn aráàlú le ní ìfọkàntán nínú wọn ṣáájú ètò ìdìbò ọdún tó ń bọ̀.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, gómìnà tẹ́lẹ̀ rí fún ìpínlẹ̀ Abia, tó tún jẹ́ alága ètò àpérò náà, Okezie Ikpeazu sọ pé ó pọn dandan kí àwọn parí aáwọ̀ tó ń wáyé nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nítorí ọjọ̀ iwájú ẹgbẹ́ náà.
Ikpeazu ní gbogbo àwọn tó bá jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tòótọ́ ló gbọdọ̀ mú ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ náà ní pàtàkì, tó sì wòye pé láti ọdún 2021 ni ẹgbẹ́ náà ti ń kojú onírúurú ìpèníjà kan tàbí òmíràn.
Ó sọ pé iṣẹ́ ńlá ló wà níwájú ìgbìmọ̀ aláṣẹ tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn náà, bí wọ́n ṣe máa ri dájú pé PDP padà sípò rẹ̀ ṣáájú ètò ìdìbò gbogbogbò tó ń bọ̀ lọ́nà.
Bákan náà ni alága tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Abdulrahman Mohammed sọ pé ohun tó máa jẹ́ àfojúsùn ìṣèjọba àwọn nib í àlááfíà ṣe máa padà sípò nínú ẹgbẹ́ náà.
Ó ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milarùn tó wáyé láìpẹ́ yìí kò túmọ̀ sí pé àwọn kan pàdánù bíkòṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ló jẹ́ fún gbogbo àwọn láti máa ṣe ohun tó tọ́ ní gbogbo ìgbà.
Bukola Saraki ní tirẹ̀ sọ pé bí àwọn aṣojú àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ wa, INEC ṣe kópa níbi ètò àpérò náà ṣàfihàn pé ìpàdé fẹsẹ̀ rinlẹ̀.
Saraki ní òun ní ìgbàgbọ́ pé ẹgbẹ́ òṣèlú máa borí níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027.
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Nyesom Wike gbóríyìn fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP bí wọn ṣe ń rí dájú pé ẹgbẹ́ náà kò di ohun àtẹ̀mẹ́rẹ̀ lágbo òṣèlú.
Ó ní pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà tí àwọn adarí ẹgbẹ́ náà ń kojú, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ní ẹsẹ̀ kùkú kò kàárẹ̀ ọkàn, tí gbogbo wọn sì mú ẹgbẹ́ náà dúró ṣinṣin.
Wike fi kun pé gbogbo àwọn tó bá wà fún ìṣọ̀kan PDP ni àwọn máa fún láàyè láti kópa ti wọn lójúnà àti gbé ẹgbẹ́ náà dé èbúté ògo.
INEC gba àwọn aláṣẹ igun Wike wọlé
Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, ti ṣe àyípadà sí orúkọ àwọn tí wọ́n gbà gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
INEC ṣe àyípadà sí orúkọ àwọn èèyàn wọn lójú òpó ayélujára wọn lọ́jọ́ Ajé, ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kẹta, ọdún 2026.
Wọ́n kó gbogbo orúkọ àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ ti igun Wike yàn gẹ́gẹ́ aláṣẹ PDP ní òpin ọ̀sẹ̀ wọ ojú òpó náà.