"Blessing CEO, dá ₦20m ti mo fun ọ lórí àrùn jẹjẹrẹ tí o sọ pé ó ń ṣe ọ́ padà" Oil Money yarí, Blessing náà fèsì

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Lati bii ọsẹ meloo kan sẹyin ni iroyin ti n tan kalẹ lori obinrin sọrọsọrọ ori ayelujara kan, Blessing Nkiruka Okoro ti ọpọ eeyan mọ si Blessing CEO.

Blessing ti ẹnu ki i sin lara rẹ lọpọ igba latari awọn ọrọ to maa n mu awuyewuye to maa n sọ lori ayelujara lo deede ke gbajare pẹlu omije loju laipẹ yii, pe oun ti lugbadi jẹjẹrẹ ọmu.

Lara awọn ti a gbọ pe o fowo ranṣẹ si Blessing CEO lati tọju ara rẹ ni Alafaa Kariboye-Igbo tawọn eeyan mọ si Oil Money, o si ti n beere adapada owo ọhun bayii.

Oil Money sọ pe ogun miliọnu loun fun Blessing, o si gbọdọ da a pada bayii laaarin ọjọ meje.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Blessing CEO, ọmọ ipinlẹ Ebonyi lo deede jade lori ayelujara to si bẹrẹ si i sunkun kikoro, to ni oun ti ni aisan jẹjẹrẹ ọmu.

Koda, o ni jẹjẹrẹ naa ti tan kalẹ, o si ti wọ ipele kẹrin arun ọhun ti a mọ si 'Stage 4'.

O ṣafihan ibi ti wọn ti n ba a fa irun ori rẹ to si tun sunkun.

Blessing CEO beere iranlọwọ awọn eeyan lati tọju ara rẹ, bẹẹ lo ni oun yoo ta ile oun pẹlu awọn wiigi olowo nla toun ni, koun le rowo tọju jẹjẹrẹ to wọle de lojiji naa.

Lati fidi ohun to n wi naa mulẹ, Blessing fi esi ayẹwo jẹjẹrẹ kan sita to fi gbe ọrọ rẹ lẹsẹ gẹgẹ bi ẹri, o ni esi ayẹwo oun niyẹn.

Awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria bẹrẹ si i dawo fun Blessing CEO

Pẹlu bi Blessing ṣe fi omije tọrọ owo to, to tun fi esi ayẹwo to pe ni tirẹ naa sita, awọn eeyan kan ko gba a gbọ, wọn ni irọ lo n pa.

Awọn wọnyi sọ pe Blessing ko le ṣorọ ki eeyan ba a bẹẹ, ati pe ko sohun ti ko le fi parọ, titi kan jẹjẹrẹ.

Ṣugbọn ọpọ eeyan lo kaanu Blessing CEO, wọn ni loootọ lo le jẹ pe ẹnu ki i sin lara rẹ, ṣugbọn ko le gboju gboya ko maa fi jẹjẹrẹ ṣere, tabi ko maa fi ẹnu ara rẹ pe jẹjẹrẹ.

Ni kiakia ni owo ti bẹrẹ si i wọle fun Blessing latọdọ awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria, ko pẹ rara to fi kede pe oun ti ri miliọnu mẹtala gba, nigba tawọn kan sọ pe ọgọrun-un kan miliọnu lo ti bọ si i lọwọ.

Ọrọ pada bẹyin yọ nigba tawọn eeyan n sọ ọ lori ayelujara, pe o yẹ ki wọn ti fọwọ ofin mu Blessing Okoro, nitori gbogbo ọrọ rẹ lori jẹjẹrẹ yii lo jẹ irọ gbuu.

Awọn kan sọ pe o yẹ ko tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria pẹlu, nitori ayederu esi jẹjẹrẹ ti ki i ṣe tiẹ lo gbe jade.

Ṣugbọn Blessing CEO ni oun ko jẹ ẹnikan kan ni aforiji, nitori oun ko fipa mu wọn lati dawo fun oun.

Lori eto tẹlifiṣan to n lọ kiri ni Blessing ti n ṣe awon alaye lori ohun to ṣẹlẹ, to si tun ni oun yoo pada sọdọ dokita oun lati mọ boya ipele kẹta ni jẹjẹrẹ naa wa loootọ.

O ni won kọkọ sọ foun pe ohun to wa lọmu oun ki i ṣe jẹjẹrẹ, igba to si tun ya ni wọn ni jẹjẹrẹ ni.

Iyẹn lo ni o mu koun ke gbajare fun iranlọwọ lori ayelujara.

Oil Money n beere owo rẹ pada lọwọ Blessing CEO

Lara awọn ti a gbọ pe o fowo ranṣẹ si Blessing CEO ni Alafaa Kariboye-Igbo, tawọn eeyan mọ si Oil Money.

Oludari ileeṣẹ elepo ni Oil Money, o si sọ pe ogun miliọnu loun fi ṣe Blessing loore nigba to kede arun jẹjẹrẹ naa.

Ninu iwe to lọwọ ofin ninu ti Oil Money fi ṣọwọ si Blessing, eyi to wa lori ayelujara lo ti kọ ọ pe:

"Da ohun ti o jẹ ni gbese pada. Da 20 million mi pada kia ko too pẹ."

Bi Blessing ba kọ lati da owo naa pada ki ọjọ meje too pe, Oil Money ni ọrọ naa yoo lati awọn agbofinro lọ, yoo si pada di ẹjọ.

"Ẹni to ba n jowu pe awọn eeyan dawo fun mi, koun naa lọ ni orukọ to pawo"

Ọpọ fidio ni Blessing ti gbe jade latigba ti ọrọ rẹ yii ti mu awuyewuye dani, lara rẹ ni eyi to ti ni orukọ ti oun ti ni lo jẹ kawon eeyan maa dawo foun.

O ni ẹni to ba n jowu pe oun rowo gba naa le lọ wa ọna ọla funra rẹ, nipa nini orukọ to pawo.

"Iwọ ti o ko dawo kankan fun mi naa n ba wọn sọ pe ki n gbe esi ayẹwo mi jade, ṣe nitori mo jade pe kawọn eeyan ran mi lọwọ.

" Orukọ lo n jẹ bẹẹ, ma jẹ ko ya ọ lẹnu pe ti mo ba ṣi fi nọmba akanti mi sita bayii, awọn eeyan ṣi maa fun mi lowo.

" O n ya yin lẹnu pe awọn eeyan fẹran Blessing, iwọ naa lo wa orukọ funra rẹ to le pese fun ọ. Ẹ maa sunkun pẹ"

Bẹẹ ni Blessing sọ ninu fidio naa.

Ọkan ninu awọn fidio rẹ lo ṣafihan ibi to ti n jẹ akàn nla, to n ṣe faaji ara rẹ lori ayelujara.

Ṣaa, ọpọ eeyan lo n pe fun mimu obinrin naa, wọn ni awọn iwa ọdaran to lodi sofin lo hu, o si ti yẹ ki wọn fọwọ ofin mu un tipẹ, to ba jẹ ilu ti ofin ti fẹsẹ mulẹ ni Naijiria ni.

Ki ni ofin Naijiria sọ lori ọrọ bi eyi?

Abala 419 ofin iwa ọdaran orilẹede Naijria, sọ pe ẹnikẹni to ba ṣe nnkan kan lori irọ, tabi ẹtan lati lu eeyan ni jibiti, tabi ji ohun kan lọwọ ẹlomi-in, jẹbi iwa to buru, o si le lọ si ẹwọn ọdun mẹta.

Abala akọkọ ọdun 2006 sọ pe ẹni to ba purọ gba owo tabi aanu kankan ti huwa ọdaran.

Ofin naa tẹsiwaju pe ko baa jẹ ilẹ okeere ni ẹni naa ti huwa yii, o lodi sofin.

Lọwọ isalẹ ofin iwa ọdaran naa, o ṣee ṣe ki ẹni to ba jẹbi rẹ ṣe ẹwọn ọdun meje si ogun ọdun, lai si aaye owo itanran kankan.

Ta a ni Blessing CEO

Ọmọ ipinlẹ Ebonyi, lapa Ila Oorun Naijiria ni Blessing Nkiruka Okoro. Ijọba ibilẹ Onitsha ni wọn ti bi i.

Orukọ to sọ ọ di gbajumọ ni Blessing CEO.

Onkọwe ni, sọrọsọrọ ori ayelujara ni, bẹẹ lo si tun maa n sọrọ lori igbeyawo ati ibaraẹnidọrẹẹ ati ibalopọ.

O bi awọn ọmọkunrin meji.

Ẹni ọdun mejidinlogun, (18) ni Blessing nigba to fẹ ọkọ rẹ akọkọ ni 2010, ọkunrin naa lo bi awọn ọmọ rẹ meji fun.

Igbeyawo naa tuka nigba ti Blessing pe ẹni ọdun mọkanlolgun (21)

Ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37) ni bayii.

Oṣu Kẹrin ọdun 2019 ni Blessing CEO ṣafihan awọn foto ile nla to ni oun kọ si Enugu, amọ ko pẹ ti Onye Eze, ẹni to ni ile ọhun fi jade pe irọ ni Blessing n pa, oun kọ lo ni ile naa, o si fi ọlọpaa mu un..

Lẹyin eyi ni Blessing ṣe fidio to fi tọrọ aforiji pe irọ loun n pa.

Nipa ajọṣe pẹlu ọkunrin, ọkunrin kan, Ikechukwu Darlington Ogbonna tawọn eeyan mọ si IVD ni wọn ni Blessing n ba dọrẹẹ, ti ọrọ naa si di ariwo nigba ti iyawo Ogbonna to n jẹ Bimbo ni oun ko ni I gba ki Blessing ni nnkan lati ṣe pẹlu ọkọ oun.

Oṣu Kẹwaaa ọdun 2022 ni Bimbo ku lojiji, ko pẹ sigba naa ni iroyin gbe e pe Blessing ati IVD ti n fẹra wọn.

Ko si pẹ sigba naa ti IVD fi ni ki Blessing jẹ kawọn gbe ifẹ awọn lọ si ipele to han saye.