"Ń ṣe ni inú mi máa ń bàjẹ́, tí mo bá rántí pé ọmọ ìyá mi ló da ásíìdì sí èmi àti ìyàwó mi lára, tí àwọ̀ ara mi fi bàjẹ́"

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọmọ ìyá kìí yà, ọmọ baba ní ń ba ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ọmọ ìyá méjì yìí.

A ò mọ̀ bóyá a le pe Promise Okwara àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kan ní ọmọ ìyá awùsá nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí ẹ̀gbọ́n Promise ṣe da ásíìdì (acid) lé òun àti ìyàwó rẹ̀ lórí, ní aago kan òru lásìkò tí wọ́n ń sùn.

Promise ṣàlàyé fún BBC News Pidgin pé lásìkò tí òun àti ìyàwó òun sùn ni ẹ̀gbọ́n òun da ásíìdì sí àwọn lára, tó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ àwọn nínú ilé, kí àwọn má lè rí ààyè jáde.

Ó ní orí ló kó òun yọ tí àwọn fi padà rí ilẹ̀kùn já nítorí ó ti ilẹ̀kùn mọ́ ìyá òun náà nítorí kí wọ́n má ba à ran òun lọ́wọ́.

Ó ṣàlàyé pé òun kò fi bẹ́ẹ̀ ríràn mọ́ nígbà tí wọ́n máa fi gbé òun jáde nítorí gbogbo ojú òun ni ásíìdì ọ̀hún dà sí.

Ó sọ pé oṣù mẹ́ta gbáko ni òun lò ní ilé ìwòsàn kí òun tó lè padà dìde.

Kí ló ṣẹlẹ̀ tí ẹ̀gbọ́n Promise fi da ásíìdì si lára?

Promise ṣàlàyé pé ní ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní, ọdún 2021 ni ìyàwó kejì ẹ̀gbọ́n òun jáde láyé, tí òkú ìyàwó rẹ̀ náà sì wà ní ilé ìgbókùúpamọ́sí.

Ó ní nígbà tí ọdún náà ń kanlẹ̀ lọ ni òun lọ bá ẹ̀gbọ́n òun pé òun fẹ́ ṣe ìgbéyàwó nígbà tó jẹ́ pé kò ì tíì ṣetán láti ṣètò ìsìnkú ìyàwó rẹ̀.

Ó sọ pé ẹ̀gbọ́n òun sọ fún òun pé kí òun lọ ṣe ìgbéyàwó òun, tí òun sì ṣe ìgbéyàwó nínú oṣù Kejìlá, ọdún 2021 kan náà.

Ó tẹ̀síwájú pé lẹ́yìn náà ni ẹ̀gbọ́n òun bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ogun ti òun pé òun kò ì tíì sin ìyàwó òun tó kú, òun lọ fi owó ṣe ìgbéyàwó.

"Ó sọ pé ó yẹ kí n kó owó ti mo fi ṣe ìgbéyàwó fún òun, kí òun lọ fi sin ìyàwó òun ni.

"Ó ní èmí àti ìyàwó mi ń sùn ní alaalẹ̀ papọ̀ nígbà tó jẹ́ pé òun nìkan ni òun ń dá sùn."

Promise tún sọ pé ẹ̀gbọ́n òun ń bá òun jà lórí ilẹ̀ kan ṣoṣo tí bàbá àwọn fi kalẹ̀ fún àwọn gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.

"Kìí ṣe pé bàbá wa ní ogún púpọ̀, ilẹ̀ kan ṣoṣo náà ni bàbá wa fi kalẹ̀ fún wa, ẹ̀gbọ́n mi náà ló sì pin fúnra rẹ̀ ní ọdún 2014.

"Ó ní òun máa mú èyí tó wà lẹ́yìn, kí èmi mú èyí tó wà níwájú ṣùgbọ́n nígbà tó fẹ́ ta ilẹ̀ tirẹ̀, ẹni tó fẹ́ rà á lọ́wọ́ rẹ̀ sọ pé ti iwájú ni òun fẹ́ tó sì padà gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ mi.

Ọkàn mi kìí balẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí pé ẹ̀gbọ́n mi ló ṣe mí báyìí

Promise sọ pé bí ara òun ṣe rí báyìí ti ní ọ̀pọ̀ ipa tí kò dára lára òun.

Ó ní níṣe nínú òun máa ń bàjẹ́ tí ọkàn òun kìí sì balẹ̀ nígbà tí òun bá rántí pé ẹ̀gbọ́n òun ló ṣe òun bẹ́ẹ̀.

Ó sọ pé ásíìdì tí ẹ̀gbọ́n òun dà sóun lára ṣe àkóbá fún imú òun èyí tí kìí jẹ́ kí òun mí dáadáa pàápàá tí òun bá ń sùn.

"Ṣẹ mọ̀ pé bí mo ṣe jòkòó báyìí mo lè ṣàkóso èémí mi ṣùgbọ́n tí mo bá sùn mi kìí lè mí dáadáa."

Ó banújẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti mú kí òun má rì í iṣẹ́ ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ nítorí èèyàn tó fẹ́ràn láti máa ṣiṣẹ́ lòun ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ fún òun mọ́.

"Ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n ni mí nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, oṣù Keje yìí ló máa pé ọdún mẹ́rin ọdún mẹ́rin, èmi ọmọ kékeré ara mi kò rí iṣẹ́ ṣe mọ́ bí mo ṣe fẹ́."

Ó ní òun nílò ìrànlọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ abẹ níbi imú òun kí òun le máa ríbi mí dáadáa nítorí òun ló jẹ òun lógún jù báyìí.

Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀gbọ́n rẹ̀?

Promise sọ pé ní kété tí ẹ̀gbọ́n òun hu ìwà ibi náà tán ló fi ẹsẹ̀ fẹ ṣùgbọ́n tí òun lọ fi ẹjọ́ rẹ̀ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá.

Ó ní lẹ́yìn ọ̀pọ̀ akitiyan, ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá padà tẹ̀ ẹ́.