You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Owó epo tún lọ sókè lágbàáyé bí Trump ṣe sọ kókó ọ̀rọ̀ mẹ́sàn-án nípa ogun US ati Iran, tó si lérí pé Amerika yóò túbọ̀ fínná mọ́ Iran lọ́nà tó lágbára sí i
Owo epo rọbi tun ti lọ soke kaakiri agbaye lẹyin ti Aarẹ Donald Trump kede pe orilẹede Amerika yoo tun ṣekọlu to lagbara si Iran.
Trump sọrọ yii lori ẹrọ amohunmaworan lalẹ Ọjọru lati ileeṣẹ ijọba Amẹrika, White House.
Trump tun rọ awọn orilẹede to n ṣiṣẹ pọ pẹlu Amẹrika wi pe ki wọn fi igboya gbe epo rọbi wọn gba ọna ori omi okun Strait of Hormuz eyi ti Iran ti gbe tipa latari ogun to n lọ lọwọ laarin Israel-Amẹrika ati Iran.
Trump ko ṣai fi idi rẹ mulẹ pe Amẹrika ko nilo lati gbe epo rọbi wọn gba ọna Strait of Hormuz to wa ni Iran.
Ọpọ onwoye lo ti sọ pe pupọ ninu ọrọ ti Trump sọ lalẹ Ọjọru ni o ti mẹnuba tẹlẹ.
Iye ti wọn n ta agba epo rọbi kan di $106 lẹyin ti Aarẹ Trump sọ ọrọ to sọ tan.
Bakan naa ni ọja kata-kara epo rọbi ja walẹ lẹkun Asia ati lawọn orilẹede ti wọn n ra epo rọbi lati ẹkun Middle East.
Ẹwẹ, agbẹnusọ fun Iran naa ti kilọ wi pe o ṣee ṣe ki Amẹrika tun ṣekọlu to lagbara si orilẹede naa laipẹ.
Ṣaaju ki Trump to sọrọ ni ileeṣẹ Iran to n ri sọrọ ilẹ okeere ti sọ pe ko si otitọ ninu ọrọ ti Trump sọ pe Iran ti n beere lọwọ Amẹrika pe ki wọn jẹ ki ogun o mi.
Ogun to n ṣẹlẹ ni Iran ọhun naa ti n fa iyapa laarin ẹbi lorilẹede Iran.
Bi awọn kan ṣe faramọ ki ogun naa tẹsiwaju lawọn mii gbagbọ wi pe ko si nnkan gidi to le jade ninu ogun to n lọ lọwọ.
Koko ọrọ ti Donald Trump sọ lori ogun to n lọ ni Iran
Ọpọ akọroyin lo ti sọ pe awọn nnkan ti Trump ti sọ siwaju naa lo tun sọ pada ninu ọrọ rẹ alẹ Ọjọru.
Wọnyii ni koko nnkan ti Aarẹ Trump sọ:
- Trump ni ileeṣẹ ọmogun Amẹrika yoo pari iṣẹ to n ṣe ni Iran laipẹ.
- Aarẹ Trump ni Amẹrika yoo ṣe ikọlu to lagbara si Iran laarin ọsẹ meji si mẹta to n bọ.
- Aarẹ Amẹrika tun kepe awọn orilẹede to n gba epo rọbi lati ẹkun Middle East wi pe ki wọn lọ fipa gba ọna Strait of Hormuz.
- Trump tun sọ pe ki iru awọn orilẹede bẹẹ maa ra epo rọbi lọwọ Amẹrika.
- Trump ni Iran ti fẹ bẹrẹ sii ṣe nnkan ijagun oloro ki Amẹrika to ba ibudo nnkan ija oloro wọn jẹ.
- Aarẹ Amẹrika tun sọ pe ti Iran ko ba le fẹnu ko ninu jiroro pẹlu Amẹrika laarin ọsẹ meji si mẹta si akoko yii, Amẹrika yoo ṣekọlu si ibudo amuṣagbara Iran.
Ko din ni ida 20% epo rọbi lagbaaye ti ọkọ oju omi agbepo n gbe gba ọna Strait of Hormuz to wa ni Iran.
Iran si ti gbe ọna Strait of Hormuz ti pa latari ogun to n lọ lọwọ, eyi to ti jẹ ki owo epo rọbi lọ soke kaakiri agbaye.