You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ fura o! Eko ni àrùn HIV pọ̀ sí jù ní Naijiria, èèyàn 2,298 ló ti ní i láàrín oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ ọdún 2026 - Àjọ NDR
Ẹka to n ri si onka ati ọrọ gbogbo to jẹ mọ kokoro arun HIV lorilẹede yii (National Data Repository), ti gbe abajade iwadii onka kokoro arun ko gboogun naa jade fun ti abala akọkọ ọdun 2026.
Ohun ti wọn fi lede lanaa Ọjọru, ọjọ kin-in-ni oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni pe kokoro arun naa pọ si ni Naijiria fun saa ti wọn wadii rẹ naa.
NDR kede pe ipinlẹ Eko ni onka awọn to ti lugbadi arun naa pọ si bayii.
Ẹgbẹrun mẹta din meji (2, 298) ni onka iye eeyan ti wọn ni HIV l'Eko bi akọsilẹ NDR ṣe sọ.
Ipinlẹ Benue to maa n saba wa nipo kin-in-ni ninu onka yii, ja walẹ ni abala akọkọ 2026.
Ti Benue ti ja pada si 1,949 bayii bi akọsilẹ National Data Repository ṣe sọ.
Apapọ onka HIV ni abala akọkọ 2026 ni Naijiria
Onka kokoro HIV lorilẹede yii fun abala akọkọ 2026 lapapọ ni wọn lo jẹ 20,838.
Laaarin oṣu Kin-in-ni ọdun yii si oṣu Kẹta ni wọn ri iye yii gbe kalẹ bii awọn to ti ni HIV ni Naijiria.
Ninu onka apapọ naa ni Eko ati Benue si ti wa ni ipo Kin-in-ni ati ikeji.
Awọn ipinlẹ yoku ti wọn tun kede onka arun HIV wọn ni :
Akwa Ibom; 1,159, Rivers; 1,137, Anambra;1,013, Kaduna;842,Sokoto 83, Yobe 97, Zamfara 139, Ogun 770, Oyo 766, Ondo 383, Osun 238, Ekiti 129.
Awọn miran ni:
Abia 529,Ebonyi –, Enugu 489, Imo 650, Bayelsa 262, Cross River –, Delta 827, Edo; 513.
Jigawa 184, Kano 462, Katsina 214, Kebbi 191, Sokoto 83, Zamfara; 139 .Adamawa 396, Bauchi 206, Borno 267, Gombe 261, Taraba 603, Nasarawa 637, Niger 396 ati Abuja FCT, 679.
"Ida 95% lo ti mọ pe awọn ni kokoro HIV"
Gẹgẹ bi NDR ṣe wi, ida "95% eeyan to n gbe pẹlu kokoro arun HIV lo ti mọ bayii pe wọn ni arun naa, yatọ si ti tẹlẹ ti ọpọ eeyan ki i tete mọ.
"Lara awọn ida marundinlọgọrun-un (95%) to ti mọ pe awọn ni kokoro naa ti n gba itọju, bẹẹ ni o to eeyan 1,657,173 to n gba itọju kaakiri awọn ibudo itọju 1,997 kaakiri."
"Ida marundinlọgọrun-un ni wọn ko le pin arun naa kiri latari itọju."
Bẹẹ ni NDR wi.
Bakan naa ni abajade naa sọ pe awọn obinrin lo lugbadi kokoro naa ju, ati pe awọn ọdọ lo fara ko o julọ ninu wọn.
Ìjọba apapọ kede $346 million owo itọju HIV, Ikọ́ ife ati arun Iba
Fun ti ọdun yii, ijọba apapọ Naijiria ti kede pe oun yoo ya $346 million sọtọ fun itọju awọn arun bii HIV, Ikọ ife ati arun iba.
Owo naa yoo wa fun ipese awọn nnkan eelo itọju, abẹwo awon yara ayẹwo, idagbasoke ile iwosan alabọọde ati aabo araalu.
Minisita eto Ilera ati alaafia, Ọjọgbọn Muhammad Pate, ṣalaye pe Naijiria n dojukọ inawo abẹle bi ile okeere ṣe n din iranlọwọ tiwọn ku.