You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba àpapọ̀ yóò san gbèsè ₦3.3trn owó iná tó jẹ láti ọdun 2015
Ijọba apapọti kede pe Aarẹ Bola Tinubu ti gbe owo ti iye rẹ to ₦3.3 tiriliọnu kalẹ ki ina mọnamọna le ṣe dede ni Naijiria.
Agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga sọ ninu atẹjade kan pe owo naa ni ijọba gbe kalẹ labẹ asia eto Presidential Power Sector Financial Reforms Programme lati san gbese ti ijọba jẹ tẹlẹ.
Onanuga sọ pe igbesẹ yii waye lati ri daju pe ina ijọba ṣe dede ni Naijiiria.
Agbẹnusọ Aarẹ ọhun ni ijọba gbe igbesẹ naa lẹyin to ti ṣagbeyẹwo gbogbo gbese ti ijọba ti jẹ ṣaaju asiko yii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, gbese owo ina ọhun ni ijọba Naijiria jẹ laarin oṣu Keji ọdun 2015 titi di oṣu Kẹta, ọdun 2025.
O ṣalaye pe igbesẹ yii bẹrẹ pẹlu ibudo to n pese ina mọnamọna marundinglogun ti iye owo rẹ to ₦2.3 trn, ijọba si ti ko ₦501b jọ lati gbọ bukata ọrọ naa.
O sọ siwaju si pe ₦223b ni wọn ti san jade ninu rẹ, ti sisan awọn to ku si ti n lọ lọwọ.
Ki itumọ igbesẹ yii fun ọmọ Naijiria?
Gẹgẹ bii alaye Onanuga, sisan owo naa yoo jẹ ki awọn ileeṣẹ to n pese ina atawọn ileeṣẹ apinaka le ṣiṣẹ bo ṣe yẹ.
Ami ti yoo si jade lẹyin gbogbo rẹ ni pe awọn ọmọ Naijiria yoo ni ina mọnamọna to ṣe dede.
Ijọba ni ti ina mọnamọna ba duro dede, awọn oludokoowo lati ilẹ okere yoo wọle si Naijiria, awọn araalu yoo ri iṣẹ ṣe, ara yoo si tu gbogbo mutumuwa.
O ni igbesẹ yii kii ṣe lati san awọn gbese ti ijọba jẹ silẹ nikan, amọ o wa fun ipese ina to duro dede faraalu.
Yatọ si sisan gbese yii, Onanuga fi kun pe awọn iṣẹ mii ṣi n bọ lọna, bii eto mita ti yoo jẹ ki araalu maa san owo fun ina ti wọn ba lo nika ṣoṣo.
O ni awọn ti ijọba n gbero lati kọkọ fun ni ina ni awọn ileeṣẹ nlanla atawọn olokoowo kekeke lọna ati jẹ ki ọrọ aje Naijiria gberu si.
O pari ọrọ rẹ pe afojusun ijọba ni ipese "ina to duro dede fun awọn eeyan ninu ile wọn, ṣiṣe atilẹyin fun awọn oniṣowo ati ṣiṣẹ ohun ti yoo mu aye dẹrun fun gbogbo ọmọ Naijiria."