Donald Trump fún Iran lọ́jọ́ méjì láti ju ọwọ́ sílẹ̀ tàbí kí òun rọ òjò iná lé wọn lórí
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ti kilọ fun ijọba Iran pe ko gba alaafia laaye laarin ọjọ meji pere, ko si ṣi aringbungbun Strait of Hormuz ti wọn n ko epo rọbi gba kọja lagbaye, bi bẹẹ kọ, yoo foju wina ohun ija oloro Amẹrika.
Trump sọ pe wakati mejiidinlaadọta pere loun fun Iran lati ṣe bẹẹ ki oun to bẹrẹ si n rọ ojo ina le orilẹede naa lori.
Aarẹ Amẹrika lo sọ ọrọ yii ninu atẹjade kan loju opo 'Truth' rẹ.
O ni " Ṣe ẹ ranti pe mo fun Iran lọjọ mẹwaa ko tọwọ bọwe adehun alaafian tabi ko ṣi oju oju ọna ori omi Strait of Hormuz.
"Akoko ti n lọ - wakati mejidinlaadọta pere lo ku ki ojo ina to bẹrẹ si n rọ le wọn lori.
"Ogo ni fun Ọlọrun. Aarẹ Donald J. Trump."
Oríṣun àwòrán, Donald Trump/Truth
Ki ni ona Strait of Hormuz?
Oju ọna Strait of Hormuz yii jẹ alagbalugbu omi to gba aarin orilẹede Iran ati Oman kọja, o si jẹ ọkan lara awọn ọna to ṣe pataki julọ lagbaye.
O kere tan, ida kan ninu marun epo rọbi ti wọn n ko kọja lagbaye lo n gba ori omi naa kọja lojojumọ.
Eyii to n tumọ si pe, ti wahala kankan tabi idiwọ ba n waye loju ọba ori omi naa, gbogbo ibi ti wọn ti lo epo bẹbtiro atawọn epo rọbi mii ni yoo ni imọ lara rẹ.
Lati ọsẹ diẹ sẹyin ni ibẹrubojo ti n waye lori ohun to ṣeeṣe ko waye loju ọna ọhun.
Ijọba Amẹrika fi awọn ọmọ ogun ranṣẹ sibẹ lati maa ṣọ awọn ọkọ oju omi nla to n gbe epo kọja nibẹ amọ Iran ni oun ko ni gba fun Amẹrika.
Ileeṣẹ iroyin BBC ti jabọ pe gbogbo igbiyanju lati pari ogun naa ni itubi-inubi lo fori ṣọpan.
Wayi o, Iran ko tii sọ ohunkohun lori gbedeke ti Amẹrika fun yii lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.
Amọ ṣaaju asiko yii ni Iran ti maa n sọ pe gbigbo aja lasan ni gbogbo idunkoko Amẹrika mọ oun.
Ti ẹ ko ba gbagbe, lati asiko ti ogun Amẹrika ati Israel si Iran ti bẹrẹ ni ọwọngogo ti de ba epo bẹntiro atawọn epo rọbi mii lagbaye.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available