Àjọ̀dún Lisabi 2026 gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lóòótọ́, àmọ́, a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mẹ́yẹ bọ̀ lápò ni - Amosun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹsẹ ko gbero nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2026 nibi ayẹyẹ ọdun Liṣabi Agbongbo Akala, ẹlẹẹkọkandinlogoji iru rẹ.

Sibẹ, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, to jẹ gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ ri sọ pe ajọdun naa yoo tubọ gbọrọgẹjigẹ si lọjọ iwaju tori awọn n ṣẹṣẹ mẹyẹ bọ lapo ni.

Sẹnetọ Amosun sọ pe "idunnu nla lo jẹ fun mi pe eto yii ti gbọrẹgẹjigẹ.

Ẹ ma gbagbe pe ikọkandinlogoji iru rẹ ree, nigba ti yoo ba fi di ogoji ọdun, iyẹn ni ọdun to n bọ, yoo tun larinrin ju bayii lọ.

Eto ti a maa ṣe nigba naa maa yatọ si ti ọdun yii.

O yẹ ki ẹ mọ pe ohunkohun to ba ti nii ṣe pẹlu ọmọ ipinlẹ Ogun, iwaju ni mo maa n wa, paapaa niluu Abẹokuta to jẹ olu-ilu ipinlẹ yii.

Wọn ti f'ẹsun kan mi lọpọ igba, onikaluku kan n sọ tiẹ ni.

Kii ṣe pe a ko ṣe ohunkohun lawọn ilu to ku, ṣugbọn a gbọdọ ṣafihan Abẹokuta gẹgẹ bi olu-ilu, ohun ti ko ye ọpọ eeyan niyẹn.''

Sẹnẹtọ Amosun fikun ọrọ rẹ pe ''gomina to ba mọ ohun to n ṣe ni lati mọ pe olu-ilu lo gbọdọ jẹ awokọṣe, to si gbọdọ dun un wo loju fun awọn olokoowo lagbaye lati wọle wa. Inu mi dun pe awọn eeyan wa mọ riri, amọran mi ni pe ki gbogbo wa ṣe ojuṣe wa bo ti tọ tori ọkan ṣoṣo ni wa niluu Ẹgba."

Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Gbadebọ, naa rọ gbogbo ọmọ Ẹgba ti wọn ko tii darapọ lati maa gbaradi fun ogoji ọdun to n bọ lọdun 2027.

Kabiyesi ni eyi ṣe pataki nitori pe ọna ara ni ayẹyẹ Liṣabi yoo tun gba yọ.

Olori ọba ilẹ Ẹgba naa sọ pe idunnu nla lo jẹ foun pe idagbasoke ti n de ba ilu Ẹgba nipasẹ ayẹyẹ ọdun Liṣabi.

Liṣabi ni jagunjagun to lewaju awọn Ẹgba kuro niluu Oyo lọdun 1830 lati tẹdo si abẹ Olumo

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gbogbo awọn ọmọ Ẹgba patapata jakejado agbaye ni wọn mura alaranbara lati fi gbe aṣa iṣembaye wọn larugẹ, eyi to tun ta wọn yọ yatọ si awọn ilẹ Yoruba yooku, ati kaakiri agbaye.

Yatọ si ojulowo awọn ọmọ Ẹgba ti wọn kopa ninu ayẹyẹ naa, awọn alejo naa ko gbẹyin nibẹ.

Liṣabi Agbongbo Akala ni jagunjagun to lewaju awọn Ẹgba kuro niluu Oyo lọdun 1830 lati tẹdo si abẹ Olumọ.

Gbogbo ọmọ Ẹgba ni origun mẹrẹẹrin to so ilu naa papọ bii Ake, Gbagura, Oke-Ọna ati Owu ni wọn figa gbaga nipa aṣọ aranbara ti wọn wọ.

Yatọ si ti aṣọ ti wọn fi figa gbaga pẹlu aṣọ, wọn tun gun ẹṣin, eyi ti wọn pe ni Ẹṣin Balogun Wọrọ ti wọn n gun lọdọọdun.

Awọn ori ade bii Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedotun Aremu Gbadebo to gba gbogbo eeyan lalejo; Oluwo tiluu Owu, Ọba Saka Adelola Matemilola; Olu Ilaro, Ọba Kehinde Olugbenle to jẹ alaga igbimọ ọba alaye nipinlẹ Ogun; Olu tilu Orile-Ilawọ, Ọba Alexander Olusegun MacGregor, ati awọn miran lo wa nibẹ.

Oloye Olusegun Obasanjo to jẹ aarẹ tẹlẹri nilẹ Naijiria, Ṣarafa Tunji Ishola ati awọn miran ni ko gbẹyin nibi akanṣe eto ọhun.