Ìwé mẹ́fà ni mo kà, kí ń tó kọ́ iṣẹ́ Rédíóníìkì, ipasẹ̀ ẹgbọ́n mi kan níbẹ̀ ni mo gbà dé ìdí iṣẹ́ tíátà - Okele

Àkọlé fídíò, Ìwé mẹ́fà ni mo kà, kí ń tó kọ́ iṣẹ́ Rédíóníìkì, ipasẹ̀ ẹgbọ́n mi kan níbẹ̀ ni mo gbà dé ìdí iṣẹ́ tíátà - Okele
Ìwé mẹ́fà ni mo kà, kí ń tó kọ́ iṣẹ́ Rédíóníìkì, ipasẹ̀ ẹgbọ́n mi kan níbẹ̀ ni mo gbà dé ìdí iṣẹ́ tíátà - Okele

Odu ni Tunde Usman, ti ọpọ eeyan mọ si Okele ninu ere sinima lede Yoruba, kii si se aimọ fun oloko.

Ta ba n sọrọ nipa awọn adẹrinposonu to wa lagbo tiata Yoruba, ọkan gboogi ni Okere nitori awọn gbankọ gbi awada to maa n se.

Idi ree ti BBC News Yoruba fi se ifọrọwanilẹnuwo fun Okele, lati mọ bi ibẹrẹ igbe aye rẹ se ri, bawo lo se de isẹ tiata, igbeyawo rẹ ati awọn ohun to se pataki si.

" N ko ni anfaani lati lọ sile ẹkọ, iwe mẹfa ni mo ka, ki n to di osere tiata"

Yoruba maa n powe pe ẹni ti yoo ga ẹsẹ rẹ yoo tiirin.

Bẹẹ ni ọrọ ri fun Okele tori ikoko ti yoo jẹ ata ni ọrọ rẹ, idi rẹ kọkọ gbona na.

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ nipa ibẹrẹ igbe aye rẹ, Okele salaye pe oun ko ni anfaani lati lọ sile ẹkọ.

O ni iwe ẹri iwe mẹfa pere ni oun ni tori lẹyin ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni oun wa si Eko.

" Nigba ti mo de Eko, mo n se oniruuru nnkan, ti mo si tun n ran iya mi lọwọ tori onisowo ata ni.

Nigba to ya, mo ni o yẹ ki n ri isẹ aje kan gbamu, tori ko dara ki ọmọkunrin ma nisẹ lọwọ, bi mo se bẹrẹ isẹ awọn to n tun redio se, ta mọ si redioniki ree.".

O salaye siwaju pe lati ara isẹ Redioniki ni oun ti sun de idi isẹ tiata tori oun ni ẹgbọn kan to n ba wọn sere tiata nigba naa.

Okele ni ọpọ igba ni ẹgbọn oun naa maa n sọ pe oun n lọ fun igbaradi fun ere tiata, ti a mọ si Rehearsal.

"Mo le sọ pe ọdọ ẹgbọn mi yii ni mo ti bẹrẹ isẹ tiata, to si tun jẹ pe lati ara ẹgbọn mi naa, ni ọrọ Okele tii se inagijẹ mi ti jade lasiko igbaradi fun ere tiata.

Bawo ni Okele se di adẹrinposonu lagbo tiata?

Nigba to salaye bo se di adẹrinposonu lagbo tiata Yoruba, Okele ni ajẹbi ni tori o dabi pe oun ni ẹbun awada ni.

"Nigba miran ti mo ba sọrọ, ẹni to sun mọ mi yoo bu sẹrin, maa si beere pe se ohun ti mo sẹ jẹ awada ni?

Ki lo jẹ awada to n pa onitọun lẹrin?

Ninu ọrọ ati iwa mi ni awọn eeyan ti fẹnuko pe adẹrinposonu ni mi."

Okele salaye pe ọrọ adẹrinposonu naa lo fa isẹ asọna, taa mọ si 'Gateman' ti wọn saba maa n fi oun si ninu ere tiata.

O fikun pe ko si abala ere sinima ti oun ko ti lee kopa ninu ere tiata amọ abala to ba wu wọn, ni ẹni to ni ere lee fi oun si.

Ipa wo ni ila to kọ n ni lori ere to n se?

Okele, lasiko to n sọrọ nipa ila mẹrin to wa loju rẹ, oun dagba ba ila loju oun ni, oun ko si le e maa lo asọ ẹha lati bo oju oun.

"Ẹlomiran ro pe tori mo kọ ila, ni mo se n se awada, rara o, ọrọ sisọ ni isẹ adẹrinposonu, kii se oju.

Boya wọn n fi ila kikọ bu mi, ko si nnkan ti mo fẹ se si tori o ti sẹlẹ naa.

"Mo wa nidi sise agbega isẹ oojọ mi lọwọ ni obinrin kan sọ fun mi pe oun ti loyun fun mi"

Bakan naa ni Okele tun salaye idi to se fẹ iyawo miran lẹyin obinrin kan to ti bimọ fun saaju.

"Mo wa nidi sise agbega isẹ oojọ mi lọwọ ni obinrin kan sọ fun mi pe oun ti loyun fun mi.

Itan to gun gba a ni lo se jẹ pe obinrin kan ti bimọ fun mi tẹlẹ, ki n to fẹ iyawo to wa ni ọdẹdẹ mi.

Oríṣun àwòrán, Okele/Instagram

Okele sọrọ lori bakan kan se n lowo ju awọn kan lọ lagbo tiata

Okele, ẹni to tun sọrọ lori idi tawọn osere tiata kan lowo ju awọn miran lọ, ni aarin ni gbogbo wa wa.

"Eeeyan ko baa maa sisẹ nibi ti wọn ti n tẹ owo, ti ko ba ni lowo, ko ni ni tori aarin ni gbogbo wa wa."

Okele tun ni oun ko le sọ boya awọn obinrin kan maa n fi idi wọn gba ipo ninu ere lati idi ibalopọ.

"Ti wọn ba ni awọn obinrin n fi idi gba ipo, ki wa ni awọn ọkunrin n lo, wọn n fi aya gba ipo?

Ẹ wo a ko le fẹ iru rẹ ku.