Kókó àbọ̀ ìpàdé tí mínísítà ààbò ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀gá àgbà ẹ̀ṣọ́ ààbò Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Ministry of Defence, Nigeria
Mínísítà fétò ààbò Nàìjíríà, Christopher Musa ti sọ pé àwọn agbèṣùmọ̀mí tó ń ṣọṣẹ́ lẹ́kùn ìlà oòrùn Nàìjíríà ni apá àwọn ọmọ ogun tó ń gbéná wojú wọn ń ká.
Musa sọ èyí nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé ìdákọ́ńkọ́ tó ṣe pẹ̀lú àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ààbò kọ̀ọ̀kan tó wáyé ní ìlú Abuja.
Ní Ọjọ́bọ̀ ni Mínísítà náà ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò sí ìpàdé látàrí báwọn agbéṣùmọ̀mí ṣe ń ṣèkọlù sáwọn ibùdó ológun ní ẹkùn ìlà oòrùn Nàìjíríà.
Láti bíi ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn báyìí ni àwọn agbéṣùmọ̀mí ti ń ṣe ìkọlù sáwọn ibùdó ọmọ ogun èyí tó ti ṣokùnfà ikú àwọn ọmọ ogun àtàwọn ọ̀gágun kan tó ń kojú àwọn agbéṣùmọ̀mí náà.
Bákan náà ni ọ̀pọ̀ àwọn agbéṣùmọ̀mí náà ti pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò àwọn ìkọlù yìí.
Ẹ ó rántí pé kò dín ní àwọn ọ̀gágun mẹ́ta tó jẹ́ ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ológun ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àwọn Boko Haram lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.
Yàtọ̀ sí àwọn ọ̀gágun tí wọ́n pa yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun náà ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí ọ̀pọ̀ aráàlú tí wọ́n jí gbé ṣì wà ní àhámọ́ àwọn agbéṣùmọ̀mí yìí.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọmọ ogun tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn, mínísítà náà sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn agbéṣùmọ̀mí náà ló ti kàgbákò ikú lọ́wọ́ àwọn ológun látàrí àwọn ìkọlù yìí.
Ó fi kun pé àwọn ọmọ ogun ní ìfarajìn sí ríri dájú pé àlááfíà àti ààbò tó péye jọba káàkiri Nàìjíríà.
Mínísítà náà ní ìpàdé náà wáyé láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìlànà tí wọ́n ń lò láti kojú àwọn agbéṣùmọ̀mí yìí káàkiri àti wá àtúnṣe sáwọn ibi tó bá yẹ.
"Gbogbo wa la mọ̀ nǹkan tó wà nílẹ̀ àmọ́ mò ń sọ àrídájú rẹ̀ fáwọn ọmọ Nàìjíríà pé àwọn ọmọ ogun ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti ri pé ààbò tó dájú wà ní gbogbo ìbú àti òró Nàìjíríà.
"Lóòótọ́ làwọn ọmọ ogun wa kan ti ṣubú lójú ìjà ṣùgbọ́n mo lè sọ fún-un yín pé ohun táwọn agbéṣùmọ̀mí kojú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀ àwọn olórí wọn la ti pa, ọ̀pọ̀ àwọn ohun ìní wọn la ti bàjẹ́, tí a sì ń tẹ̀síwájí."
Ẹ yé pín fídíò àwọn agbéṣùmọ̀mí lórí iléeṣẹ́ yín mọ́ - Musa sọ fáwọn akọ̀ròyìn
Ó wá rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti má jẹ̀ẹ́ kí àwọn ìròyìn tí wọ́n ń gbọ́ lórí ayélujára da omi tútù sọ́kàn wọn, bó ṣe ní àwọn ìròyìn òfégè tó ń ló lórí ayélujára le kó ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá àwọn ọmọ ogun tó wà lójú ìjà.
Bákan náà ló rọ àwọn aráàlú láti máa ṣe kóríyá fáwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò nípa pípèsè àwọn ìròyìn tó le ṣèrànwọ́ fún wọn nígbà tí wọ́n bá kẹ́fín ìwà kòtọ́ kan ní agbègbè wọn.
Musa fi kun pé gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò míì ló ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ológun láti ṣe ìrànwọ́ fún wọn lórí ogun tí wọ́n ń gbéti àwọn agbéṣùmọ̀mí.
Nígbàt ó ń kí ọ̀gá iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà kú oríire fún ìyànsípò rẹ̀ ó sọ pé iléeṣẹ́ ológun ṣetán láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá láti kojú ìpèníjà ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra.
Ó wá rọ àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn láti máa ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú bí wọ́n ṣe máa ń pín àwọn fọ́nrán táwọn agbéṣùmọ̀mí bá gbé síta lórí ìkànnì wọn nítorí ó le jẹ́ ìwúrí fáwọn èèyàn náà láti máa tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìwà ibi wọn.
"Bí ẹ bá ṣe ń pín àwọn fídíò wọn lórí ìkànnì yín dàbí pé ẹ̀ ń kan irin mọ́ wọn lápá, tí wọ́n yóò sì máa lò ó tako àwọn ọmọ ogun."
Mínísítà náà tún ṣèkìlọ̀ fáwọn aráàlú tó ń ìrànwọ̀ fún bí àwọn agbéṣùmọ̀mí náà ṣe ń bọ́ láti ibìkan sí ibòmíràn tàbí tí wọ́n ń tú àwọn àṣìrí àwọn ọmọ ogun fún wọn láti so agbéjẹ́ mọ́wọ́ nítorí tí ọwọ́ bá tẹ̀ wọ́n, ìjìyà táwọn agbéṣùmọ̀mí ń kojú ni irú àwọn bẹ́ẹ̀ náà máa kojú.
Lára àwọn tó kópa níbi ìpàdé náà ni ọ̀gá àgbà àwọn òṣìṣẹ́ ààbò Ọ̀gágun Olufemi Oluyede, Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun,Ọ̀gágun Waidi Shaibu, Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun òfurufú, Sunday Aneke, Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun orí omi, Idi Abass, aṣojú àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.


























