Àṣìta ìbọn ṣekúpa ọ̀dọ́binrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá nínú ilé, ìwádìí bẹ̀rẹ̀
Oríṣun àwòrán, Amnesty International Nigeria/X
Aṣita ibọn ti ṣekupa ọdọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrinla kan niluu Maiduguri nipinlẹ Borno.
Lopin ọsẹ to kọja ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ nigba ti ọmọdebinrin naa wa niluu ile pẹlu ẹbi rẹ nile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti Maiduguri, UMTH.
Ajọ Amnesty International sọ pe ọta ibọn awọn sọja kan ti wọn n fi idunnu yinbọn soke nibi ayẹyẹ igbeyawo kan lo lọ ba ọmọbinrin naa ninu ile.
Amọ, oju opo kan to maa n fi oriṣiiriṣii fidio sori ayelujara nipa awọn ọmogun sọ pe ikọ fijilante, CJTF, lo yinbọn ọhun.
Ikọ ọmogun Operation Hadin Kai naa sọ pe ikọ fijilante CJTF lo yinbọn ọhun, kii ṣe awọn sọja.
Ọga ikọ naa ni iwadii awọn fi han pe awọn fijilante lo n yinbọn soke ti wọn fi n daawọ ayẹyẹ igbeyawo kan to n lọ ninu ile kan.
O ni lati ibẹ ni ọta ibọn ti lọ ba ọdọbinrin to wa niluu pẹlu ẹbi rẹ.
Ileeṣẹ ologun ni iwa aibikita ni awọn to yinbọn naa hu, ati pe ileeṣẹ ologun ti bẹrẹ iwadii lati mọ awọn to yinbọn to pa ọmọdebinrin naa.
Ikọ Operation Hadin Kai ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi ọmọdebinrin naa, wọn si tun rọ awọn eeyan wi pe ki wọn ye gbe iroyin ofege kiri lori iṣẹlẹ naa.
Ẹnikan to sun mọ ẹbi ọmọdebinrin naa ṣalaye wi pe ninu idunnu ni ọmọ naa wa ki ọta ibọn to lọọ ba a.
Ijọba gbọdọ pese eto aabo to peye fun araalu – Amnesty International
Awọn ẹbi ati ọrẹ n beere fun iwadii to fẹsẹ mulẹ lori iṣẹlẹ naa, lẹyin ti wọn sin oku rẹ lanaa ọjọ Aiku.
Ajọ Amnesty International naa koro oju si iṣẹlẹ ọhun, wọn si ti kepe ijọba lati ṣewadii nnkan to ṣẹlẹ gan an.
Ajọ Amnesty International rọ ijọba ninu atẹjade kan to fi sita lati kede abọ iwadii iṣẹlẹ naa ki gbogbo eeyan le mọ ohun to ṣẹlẹ gan an.
Amnesty International ni ijọba gbọdọ pese eto aabo to peye fun araalu, ki wọn si fọwọ ofin mawọn to ba wa nidi iwa ibajẹ.
Iṣẹlẹ yii tun ti jẹ ki ọpọ eeyan maa kọminu lori bawọn eleto aabo ṣe maa n fi ibọn yinyin dawọọ tori ewu to wa nibẹ.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available