Amritsar: Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sọnù sínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú'rin lásìkò tí wọ́n n wòran ọdún

Àkọlé fídíò, Fidio yii n ṣafihan ayẹyẹ naa ki ijamab ọhun to waye
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

O lé ni aadọta eniyan to padanu ẹmi wọn, ti eniyan igba mi i si tun farapa lasiko ti ọkọ oju'rin kan yà wọ aarin awn ero to n woran nitosi ilú Amritsar.

Ọnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ fun BBC pe awọn to padanu ẹmi wọn ọhun duro ni oju ọna ọkọ oju'rin lati woran ayẹyẹ ọdun Hindu to jẹ ti Dusshera

Wọn ko si gbọ ìrò ọkọ naa nitori pe ariwo ina alarambara ti wọn tan sinu ère oriṣa Ravana ti wọn n wo lọwọ.

Awọn alaṣẹ sọ pe nkan to jẹ wọn l'ogun lọwọlọwọ ni lati gbe awọn to farapa lọ sileewosan fun itọju.

Oríṣun àwòrán, EPA

Fidio kan to wa lori ẹrọ ayelujara ṣafihan bi ọkọ oju'rin naa ṣe kọlu àwọn eniyan ọhun.

Just moments before, crowds watching the firecrackers show were asked by organisers to move back - towards the railway tracks, reports say.

Ọkọ oju'rin naa n rinrinajo lati ilu Jalandhar lọ si Amritsar.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Lasiko ti awọn araalu n ṣayẹyẹ ọdun Hindu ni ọkọ naa lọ kọlu wọn

Minisita fun ilu Punjab, Amarinder Singh ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹg bi ohun to bani lọkan jẹ pupọ.

''Ao ṣe gbogbo nkan to yẹ lati ran awn to farapa lọwọ.''

"Mo si ti paṣẹ fun awọn alakoso agbegbe naa lati ri daju pe nkankan ko mẹ́hẹ ninu itọju wọn."

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Awọn to le ni igba lo farapa

Bakan naa ni olootu ijọba, Narenda Modi, sọ̀ pe iṣẹlẹ naa jẹ ibanujẹ ọkàn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ẹwẹ, àwọn eniyan n bẹru pe o ṣeeṣe ki awọn ti yoo ku tun pọ si.

Ijamba ọkọ oju'rin wọpọ diẹ ni orilẹede India, nibi ti awọn oju'rin ti di ti atijọ, botilẹ jẹ wi pe o ti dinku ni asiko yii.

Kini Ọdun Dusshera duro fun?

Oríṣun àwòrán, EPA

  • Ayẹyẹ fun bi oriṣa Hindu, Rama ṣe bori ooṣa olori mẹrin, Ravana
  • O n ṣafihan iṣẹgun ti ire ni lori ibi
  • Ọdọọdun ni wọn maa n ṣe e - o si maa n waye fun oru ọjọ mẹwa gbako
  • Lọdun 20015, ajọ Unesco gbe ade fun àṣà Ramlila gẹgẹ bi ''Nkan ajogun ba to gbayi laarin ọmọniyan''