Police brutality: Tola ní inú òun kò bá dùn tí wọ́n bá le fi àwọn ọlọ́pàá tó lù òun jófin yàtọ̀ sí 5m tí wọ́n fẹ́ fún òun

Oríṣun àwòrán, Twitter/Abiodun Sonaike

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ileẹjọ giga niluu Osogbo ti dajọ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa san miliọnu marun naira fun ọmọbinrin kan, Tola Azeez lẹyin ti awọn ọlọpaa fiya jẹ ẹ lasiko kole-o-gbele arun coronavirus.

Azeez niwaju ile rẹ lawọn ọlọpaa kan ṣadeedee ri, ti wọn si lu u lalu bami lai ṣẹṣẹ kan.

Fidio bi wọn ṣe lu u nilu bara gba ori ayelujara kan lọdun to lọ.

Tola ni oun ni lati fi ilu ti oun n gbe nigba naa silẹ lati lọ tọju ara oun niluu ibo mii.

O ṣalaye pe ṣaaju iṣẹlẹ naa, oun jẹ ẹnikan ti kii fẹ kawọn eeyan ṣaaba mọ nipa oun to n ṣẹlẹ si oun.

Ṣugbọn o ni inu oun dun pe ileẹjọ ni ki wọn fun oun ni miliọnu marun un.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Amọ o ni inu oun ko ba dun si ti wọn ba le fi ọlọpaa to fiya jẹ oun jofin ko lo jẹ arikọgbọn fawọn mii to ba hu iru iwa bẹẹ.