Èkó: Ẹ́ san owó orí lóríi ilé tẹ́ẹ sọ di iléèjọsin

Oríṣun àwòrán, LASG

Àkọlé àwòrán, Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ní ọgbọ́n àti sá fún owó orí sísan ni áwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ń dá

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti f'ohùn sílẹ̀ pé kò sí ààyè fún sísọ iléègbé di iléèjọsìn mọ́ ní ìpínlẹ̀ náà.

San owó orí bí ó ti yẹ

Kọmíṣọ́nà fọ́rọ̀ abẹ́lé, Abdul Hakeem Abdul Lateef ló sọ èyí nílùú Èkó.Ó ní Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti kẹ́ẹ́fín pé àwọn onílé kan ń sọ ilé wọn di ilé ìjósìn lọ́nà àti sá fún sísan owó orí ilẹ̀ àti ilé níbẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, "fún àwọn tó ń lo ilé wọn fún ilé ìjósìn, mọ́ṣáláṣí tàbí ṣọ́ọ̀ṣì, a ko ni wo ile bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n bi a ti sọ ṣaaju, gbogbo ile ni yoo san owo ori ileegbe ati ilẹ̀.

Ẹ ko gbọdọ̀ sọ pé mọ́ṣáláṣí tàbí sọ́ọ́sì wa nisalẹ ile yin

Bi àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba bá de, ẹ ko gbọdọ̀ sọ pé mọ́ṣáláṣí tàbí sọ́ọ́sì wa nisalẹ."O ni gbogbo ile ti won ba kọ̀wé rẹ̀ fún ìjọba gégébí iléègbé ni yóò san owó orí yìí.