Fídíò ‘Sharwama’, ọkùnrin tó ní òun ti pa èèyàn 32 gba orí ayélujára, Ọlọ́pàá Oyo sọ̀rọ̀

Shawarma atawọn ọrẹ rẹ lasiko to sọrọ naa

Oríṣun àwòrán, Sahara Reporters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti ni oun ti bẹrẹ iwadii fidio kan to n mi ori ayelujara titi nibi ti ọkunrin kan ti sọ pe eeyan mẹtalelọgọn loun ti gbẹmi wọn.

Ọkunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Shawarma sọ pe ọlọpaa atawọn ologun ri oun lẹyin ti oun gbẹmi awọn eeyan naa ti wọn ko si fi oun ṣe nnkankan.

Ninu atẹjade kan, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka sọ pe ileeṣẹ naa ko ni akọsilẹ kankan pe wọn pe awọn fi ṣikun ofin mu Sharwama ri, lodi si ọrọ to n lọ lori ayelujara.

O fi kun pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori fidio naa, paapaa lori awọn ọrọ ti ọgbẹni ọhun sọ nibẹ.

Gẹgẹ bii ọlọpaa ṣe sọ, awọn yoo lo oniruru ẹrọ igbalode lati ṣewadii fidio naa lọna ati mu okodoro jade nibẹ.

Atẹjade naa tẹsiwaju pẹlu arọwa si awọn araalu lati pese iroyin to le ṣamọna bi wọn ṣe le da ọkunrin naa mọ ki awọn le tete gba mu lati wa sọ tẹnu rẹ.

Lẹyin naa lo ni ọlọpaa yoo tẹsiwaju lati maa bun araalu gbọ nipa bi iwadii naa yoo ṣe lọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ki ni Shawama sọ ni pato?

Ninu fidio naa to n milẹ titi lori ayelujara lọwọ ni ọkunrin meji, ti ọkan ninu wọn wọ aṣọ ipolongo ẹgbẹ oṣelu APC pẹlu fila, nigba ti afurasi, Shawarma, wọ aṣọ dudu.

Ọkunrin to wọ aṣọ APC sọ pe "Shawarma, eeyan melo lo ti pa ni Ibadan bayii?"

Shawarma fesi pe "Wọn fẹ pa wa o, wọn fẹ ṣe yanmayanma si wa n'Ibadan, a yi mọ wọn lọwọ, mo pa eeyan mẹtalelọgbọn.

"Ọlọpaa ri mi o ni ki n maa lọ sile, o ni mo gbiyanju, ologun ri mi, wọn ni mo gbiyanju, wọn ni wọn fẹ pa mi amọ mo gbiyanju."

Lẹyin naa ni ọkunrin to n ba Shawarma sọrọ sọ fun pe "Shawarma, ma paayan mọ o."

Lẹyin naa ni awọn ọkunrin mejeji atawọn mii to wa nibẹ bẹrẹ si n pariwo pe Aarẹ Bola Tinubu ni yoo wọle ibo Aarẹ ọdun 2027.

Wọn ni" Asiwaju 2027, ọga tiwa, b'oo tilẹ dibo, o ti wọle."

Nibo ni Sharwama wa bayii?

Nigba ti BBC Yoruba kan si ileeṣẹ ọlọpaa Oyo, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa naa, Olusola Ayanlade sọ fun wa pe awọn ti bẹrẹ si n wa ọkunrin naa, ọwọ si maa tẹ ẹ laipẹ ọjọ.

O ni o ṣoro lati mọ ibi ti afurasi naa wa lati inu fidio ọhun amọ awọn yhoo lo ẹrọ igbalode lati ṣawari rẹ.

Ayanladde ni ọwọ yoo tẹ afurasi ọhun "titi ọsẹ to n bọ, yoo si wa wi tẹnu rẹ" to ba de agọ awọn.