Pakistan yin àdó olóró mọ́ Afghanistan, èèyàn 100 jóná kú, 2000 farapa

Ibugbamu Omid Addiction Treatment Hospital

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O le ni ọgọrun eeyan to jade laye lẹyin ti ado oloro orilẹede Pakistan kan balẹ sibi ti wọn ti n tọju awọn to n lo oogun oloro niluu Kabul, ni Afganistan.

Awọn oluwadii to ba BBC sọrọ lati ajọ Kabul Forensic Medicine sọ pe awọn eeyan kan jona kọja didamọ nibi ikọlu ọhun.

Awọn ọmọ ogun Taliban sọ pe iye eeyan to jade laye ninu ikọlu naa pọju bẹẹ lọ, ajọ UN si ti parọwa pe ki wọn bẹrẹ iwadii lori ikọlu naa.

Ijọba orilẹede Pakistan ti ni kii ṣe pe oun mọọmọ kọlu gbagede naa amọ ibudo awọn ologun atawọn agbesunmọmi loun n dojukọ.

"Ẹgbẹrun meji eeyan n gba itọju nile iwosan"

Oṣu to kọja ni ija bẹrẹ laarin orilẹede mejeji, Pakistan ni Afganistan n daabo bo awọn agbesunmọmi to kọlu ilẹ oun ṣaaju, amọ Kabul ti fesi pe ko si ohun to jọ bẹẹ rara.

Ajọ UN Assistance Mission in Afghanistan (Unama) ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu naa eyii to sọ pe ileeṣẹ ọmọ ogun Pakistan ṣe si ibudo itọju awọn to n lo oogun oloro, iyẹn Omid Addiction Treatment Hospital.

Unama sọ ninu atẹjade kan pe ẹbẹ awọn ni ki ija naa dopin ki igun mejeji si ṣe ohun to yẹ labe ofin agbaye lati le daabo bo awọn araalu.

Nnkan bii ẹgbẹrun meji eeyan lo n gba itọju nile itọju naa gẹgẹ bii ohun ti ọkan lara awọn oṣiṣẹ ibẹ sọ.

Oṣiṣẹ naa ni awọn to ku nibẹ to ọgọgọrun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ eto ilera Afganistan, Sharafat Zaman Amarkhail, sọ fun BBC pe ko si ibudo ologun kankan lẹba ile itọju awọn oloogun oloro naa.

Ọpọ awọn mọlẹbi awọn to n gba itọju naa ni wọn korajọ siwaju ibudo itọju ọhun lati bere nipa ipo ti awọn ẹbi wọn wa.

Agbẹnusọ Taliban sọ pe eeyan to ku nibẹ le ni irinwo amọ awa gẹgẹ bii ileeṣẹ iroyin BBC ko le fidi iroyin naa mulẹ.

Awọn adoola ẹmi ṣi n ṣiṣẹ nibẹ lati doola awọn eeyan lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.