Aṣọ́bodè méjì tó fìbọn lé awakọ̀ kiri lójú pópó l‘Osun, títí tó fi kú, kó sí gbaga

Aworan awọn osiṣẹ asọbode

Oríṣun àwòrán, Nigeria Custom

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun ni awọn ti ri iroyin gba lori ọkunrin kan ti wọn yinbọn pa ni opopona ọna Iwo- Osogbo lọjọ aiku.

Iṣẹlẹ naa waye ni ọjọ Kẹẹdogun oṣu kẹta ọdun 2026.

Ileeṣẹ ọlọpaa si jẹ ko di mimọ pe awọn afurasi to lọwọ ninu iku ọkunrin naa ti wa ni ahamọ ati awọn ọlọpaa to wa ni opopona lasiko naa wa nibi ti wọn ti n wi tẹnu wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ẹsọ alabo wa ni opopona ti iṣẹlẹ naa ti waye, ti ọwọ si ti tẹ awọn ẹsọ aṣobode ti wọn yin bọn fun oloogbe naa.

Agbegbe Onibueja ni Ido-Osun, nipinlẹ Osun ni awọn asọbode ti yinbọn fun awakọ naa.

Ninu fidio to tẹ wa lọwọ, ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye sunmọ ibudo awọn ọlọpaa to wa ni opopona ni deede aago mẹwaa.

Awọn oṣojumikoro to ba ileeṣẹ iroyin abẹle, The Punch sọrọ, ṣalaye pe awọn asọbode naa ni wọn ko wọ aṣo iṣẹ lasiko ti wọn ṣe iṣẹ yii, ti wọn si bẹrẹ si ni ma le oloogbe titi to fi di opin ọna.

Lẹyin iwadii ni aṣiri tu pe oṣiṣe asọbode orilẹede Naijiria ni awọn afurasi naa.

Bakan naa ninu fidio to tẹ wa lọwọ, ọkọ oloogbe naa lo jẹ pe wọn ti fi ibọn ba bajẹ, ti awọn ọdọ agbegbe si jade sita lati doju ija kọ awọn asọbode.

Awọn ọdọ yii ti wa kesi ijọba lati kede orukọ awọn asọbode naa, ki wọn si fiya jẹ wọn labẹ ofin.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipilẹ Osun, Abiodun Ojelabi, ni orukọ awọn asọbode naa ni; Kolawole Suuti ati Danjuma Samuel.

Ojelabi tẹsiwaju pe orukọ oloogbe naa ni Anayo Azikwe Micheal to si wa lati ipinlẹ Delta.

"Oloogbe yii wa lati ipinlẹ Delta. Orukọ rẹ ni Anayo Azikwe Michael, ẹni ọdun Mọkanlelogoji," Ojelabi ṣalaye.

O fikun pe awọn mọlẹbi oloogbe naa ti wa si ipinlẹ Osun lati wa gbe oku ẹbi wọn.