CAF gba ife ẹ̀yẹ AFCON 2025 lọ́wọ́ Senegal, gbé e fún Morocco

Sadio Mane mu ife ẹyẹ AFCON 2025 dani bawọn akẹgbẹ rẹ ṣe gbe e soke, Achraf Hakimi n woke

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ CAF to n ṣakoso ere bọọlu nilẹ Afirika ti gba ife ẹyẹ ìdíje AFCON 2025 ti ẹgbẹ agbaboolu Senegal gba, wọn si ti gbe e fun ikọ agbábọ́ọ̀lù Morocco bayii.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Senegal fagba han Morocco pẹlu ami ayo kan sodo ninu ere bọọlu asekagba idije naa lati gba ife ẹyẹ ọhun.

Àjọ CAF ṣàlàyé loju opo X rẹ pe igbesẹ yìí ko ṣẹyin bi awọn agbaboolu Senegal ti binu kuro lori papa lẹyin ti refiri fawọn Morocco ni pẹnairiti nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa.

Bo tilẹ jẹ wipe ẹlẹsẹ ayo, Sadio Mane to jẹ ọkan lara awọn agbaboolu Senegal ko kuro lori papa ni tiẹ, CAF ni Senegal ti mofo niwọn igba ti wọn ti binu jade lori papa.

Lẹyìn tí Brahim Diaz sọ penariti ti wọn fun Morocco nu ni Pape Gueye gba goolu kan ṣoṣo ti Senegal fi bori s'awọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post