COVID-19, Ẹ fọkàn balẹ̀ ìjọba Nàìjíríà kò ni jẹ́ kí Coronavirus tàn kálẹ́ rára- Minisita ìlera
Oríṣun àwòrán, Others
Minisita fun Ilera, Dokita Osagie Ehanire ti ṣalaye pe Ijọba apapọ n sa gbogbo agbara rẹ lati dena itankalẹ aarun COVID-19 titun ni orilẹ-ede yii.
Ehanire sọ eyi ni akoko ti oun ba awọn akọroyin sọrọ lori ibiti igbaradi ijọba de lori itakalẹ ẹya COVID-19 titun.
Minisita salaye pe ile-iṣẹ to risi ilera ti pade pẹlu Ajo ilera Agbaye ati asoju orilẹ-ede China si Naijiria lati ṣe atunyẹwo awọn iṣẹlẹ titun lori aarun COVID-19 ni Ilu China.
Ehanire sọ pe “itankalẹ aarun COVID-19 ni Orilẹ-ede olominira China pe fun ijiroro laarin Orilẹ-ede yii ati China .
O ni itankalẹ COVID-19 ni Orilẹ-ede Amerika,China ati yuropu ni akoko otutu yii ko je titun.
Minisita fun ilera nii, Orilẹ-ede Naijiria ti gbe igbese akin lati ri wi pe gbogbo ọna abawọle si Orilẹ-ede yii ni o wa ni igbaradi lati kefin aarun COVID-19 laara awọn ti o wọọ Orilẹ-ede yii wa.
Ehanire ro awọn ọmọ orilẹede yii lati gba abere ajesara COVID-19 ati lati lo ibomu nigbati wọn baa wa ni aarin eniyan pupọ.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available