Arugba ti dé ojúbọ odò Osun níbi ayẹyẹ àṣekágbá ọdún Osun Osogbo 2025

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọdọọdun laa ri orogbo, ọdọọdun laa ri awusa, ọdọọdun si laa ri ọmọ obi lori atẹ, amọdun ko si jinna, kẹni ma ri eebu sun jẹ.

Bẹẹ lọrọ ri pẹlu ọdun Ọṣun Ọṣogbo fun tọdun 2025, eyi to ti bẹrẹ fun bi ọsẹ kan bayii.

Ara awọn eto ti wọn fi n sami ọdun Ọṣun Ọṣogbo si ni ipejọpọ awọn arugba ni aafin Ataoja tilu Osogbo eyi ti a waye bayii.

Bi ọdun Ọṣun Osogbo ṣe jẹ pataki to, to si jẹ ọdun ti awọn eeyan n ti n oke okun waa ṣe nipinlẹ Ọṣun, abala kan wa nibẹ ti ko gbọdọ ma waye, eyi ni abala Omidan to n ru igba Oriṣa Ọṣun Osogbo.

Ọmọbinrin ti ko ti i mọ ọkunrin lo maa n ru igba Ọṣun Osogbo, idile ọba lo si ti gbọdọ wa.

Mimọ, ai ni abawọn ati funfun ni Orisa Ọṣun funra rẹ duro fun, eyi lo si fa a to fi jẹ pe ọmọge ti ko mọ ọkunrin lo maa n ru igba Ọṣun.

Ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹsan an to jẹ Arugba Osun tuntun, ti wọn pe orukọ rẹ ni Osunbunmi, ti ru igba lọ si ojubọ Osun-Osogbo.

Ọmọdebinrin naa ti ko mọ ọkunrin, ru igba naa to kun fun awọn nnkan etutu ọdọọdun fun oriṣa Osun.

Aṣoju Ọṣun Osogbo ni Arugba, oun ni yoo ru igba nla kan ti wọn ṣe ipese ọlọkan-o-jọkan sinu rẹ, ọpọ eeyan yoo si tẹle e lẹyin.

Kabiyesi Ataoja lo kọkọ gbadura fun Arugba ki o to o bẹrẹ si ni ya awọn ibi ti arugba maa n de lọdọọdun ki o to morile ojubọ odo Osun.

Àkọlé àwòrán, Baba Osun re e to ru igba naa sori, ti awọn ọmọlẹyin Osun si n ran an lọwọ
Àkọlé àwòrán, Yatọ si ajọyọ fun Osun, oriṣiriṣi awọn nnkan iṣẹmbaye ni awọn eeyan tun ma n ri i ra nibi ọdun naa
Àkọlé àwòrán, Aṣọ funfun ni ọpọ awọn to n bọ oriṣa Osun ma n wọ layajọọ OSun-Osogbo
Àkọlé àwòrán, Aafin Ataoja ilu Osogbo ni Arugba yoo kọkọ lọ, ko to o bẹrẹ irinajo rẹ si ojubọ Osun
Àkọlé àwòrán, Arugba tuntun re e, Osunbunmi, ọmọ ọdun mẹsan an, lasiko to n gbaradi lati ru igba Osun