Àwọn àwòrán mánigbàgbé láti ibi ìsìnkú Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Olawale Abolade

Àkọlé àwòrán, Iyawo, àwọn ọmọ ati ọmọ-ọmọ oloogbe Rotimi Akeredolu duro leti iboji láti dagbere

Oríṣun àwòrán, Olawale Abolade

Àkọlé àwòrán, Iyawo oloogbe, Arabinrin Betty Akeredolu rèé to n bu erupẹ sì oku ọkọ rẹ ninu iboji
Àkọlé àwòrán, Igbakeji aarẹ Naijiria,Kashim Shettima naa wa sibi eto isinku Akeredolu niluu Owo
Àkọlé àwòrán, Gomina ipinlẹ Eko,Eko, Babajide Sanwo-Olu, wa lara àwọn gomina to ṣe ẹyẹ ikẹyin fun akẹẹgbẹ́ wọn to lọ
Àkọlé àwòrán, Gomina ipinlẹ Kano nigba kan, Abdullahi Ganduge, naa kopa nibi eto isinku Akeredolu

Oríṣun àwòrán, BBC

Àkọlé àwòrán, Wọn fi aṣọ iṣẹ awọn ẹsọ alaabo Amotekun ṣe ẹyẹ ikẹyin fun Akeredolu. Ipa kekere kọ ni oloogbe naa ko ninu idasilẹ ileeṣẹ alaabo naa nilẹ Yoruba
Àkọlé àwòrán, Inu ọgba yii ni wọ́n sin Rotimi Akeredolu si niluu Owo, to jẹ ilu abinibi rẹ

Oríṣun àwòrán, Bbc

Àkọlé àwòrán, Gbogbo oju ọna ni awọn eeyan pe si lati wo Akeredolu fun igba ikẹyin

Oríṣun àwòrán, Bbc

Àkọlé àwòrán, Tọmọde-tagba lo tu yaaya jade si oju ọna lati wo Akeredolu fun igba ikẹyin
Àkọlé àwòrán, Iyawo ati ọmọkùnrin Akeredolu niyii ninu ile ijọsin St. Andrews Cathedral, Owo
Àkọlé àwòrán, Pẹlu ẹdun ọkàn ati ikaanu ni àwọn araalu Owo fi dagbere fun ọmọ wọn, Rotimi Akeredolu to d'oloogbe