Ẹlẹ́sìn Aghoris: Wọ́n ń jẹ ènìyàn, wọn a sì fi orí rẹ̀ mumi
Oríṣun àwòrán, EPA
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ń tẹ̀lẹ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n bá òkú lòpò yíí, tí wọ́n sì ń jẹ ẹran ara ènìyàn.
Awọn ẹlẹsin Hindu yii ma n woye bii nkan yoo ṣeri pẹlu arojinlẹ,ti wọn si maa n jẹun, sun ati ni ibalopo laarin awọn oku ti wọn n jo ni ina ni itẹ iboji.
Awọn wọnyii maa n rin kaakiri lai wọ asọ, wọn maa n jẹ ẹran ara eniyan ti wọn a si ma a fi agbari eniyan ṣe igba imumi ati ti ounjẹ, ati pe oogun oloro marijuana ki n wọ́n lọwọ wọn lasiko naa.
Asiko ọdun iwẹ awọ̀n elesin Aghoris nikan ni wọn máa n jade ni Ọjọ Kẹẹdogun, osu kini, odun ni orilẹ-ede India ti wọn n pe ni ọdun Kumbh Mela.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọ̀pọlọpọ̀ eniyan lo n tẹle awọn okunrin ti wọn ba oku lọpọ yii, ti wọn si n jẹ ẹran ara eniyan.
Oríṣun àwòrán, EPA
Ni ede Sanskrit, ohun ti orukọ Aghori duro fun ni ‘ẹni ti ki n ba eniyan lẹru’, amọ awọn ohun ti o n banilẹru ti wọn n gbọ nipa wọn maa n fa ibẹrubojo ati irira nipa wọn fun awọn eniyan.
Oríṣun àwòrán, Empics
Ohun to yẹ ko o mọ nipa awọn ẹlẹsin Aghoris ni India
- Ihuwasi wọn da bi ẹni wi pe wọn sẹṣẹ bẹrẹ ẹsin naa ni saa nkan bii ẹgbẹrun un ọdun mejidinlogun (18th century) sẹyin ni.
- Ohun ti wọn gbagbọ ni wi pe eniyan ko gbọdọ bẹru iku tabi oku ni wọn se n jẹ eniyan lati bori ibẹru iku.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Iwadii fihan wi pe awọn ko gbagbo nipa ikorira ọmọlakeji.
- Awọn ti wọn n se ẹsin yii ko pọ rara. Wọn fikun un pe awọn ti wọn n darapọ mọ ọdun Kumbh Mela kii se awọn ti o jinlẹ ninu ẹsin naa.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Bakan naa ni wọn maa n sisẹ ilu nipa titọju awọn oni warapa ni itẹ ti wọn maa n gbe oku si ati ile iwosan wọn.
- Amọ wọn korira ibalopọ laarin akọ si akọ, wọn rii gẹgẹ bi ohun irira.
Oríṣun àwòrán, EPA
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available