Oyo PDP Primary: Ta ni yóò jáwé olúborí láàrin Seyi Makinde àti Gbolarumi Hazeem níbi ètò abẹ́nú PDP?

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, @Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde, ti wọle lati dije  du ipò gómìnà fun ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party PDP nibi  eto idibo abẹlẹ ti wọn ṣẹṣẹ pari ni papa iṣere Lekan Salami, ni ìlù  Ìbàdàn.

Makinde ni ibo  egberun lona ogoji (1,040 ) lati bori oludije re, Ogbeni Hazeem Gbolarunmi, eni to ni ibo meji.(2)

Idibo ofo mẹfa wa lapapọ ninu ibo ti 1,048 ti wọn  ka

Nínú  ọrọ  àpilẹ̀kọ  rẹ  Seyi Makinde ṣèlérí  ìdàgbàsókè  tuntun  kaa Kírì  ipinlẹ  Ọ̀yọ́  gege bi  o ti ṣe  láàrín  odun mẹta  tí  o n lo lo yii.

Seyi Makinde àti Gbolarunmi Hazeem

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ sẹyin?

Ta ni yóò jáwé olúborí láàrin Seyi Makinde àti Gbolaruni Hazeem níbi ètò abẹ́nú PDP?

Ẹgbẹ  òsèlú Peoples Democratic Party, PDP tẹka ipinle  Ọ̀yọ́ yoo ṣe eto ìdìbò abẹ́nú  fun ipò gómìnà ni gbàgede  Adamasingba lonii.

Àkọlé fídíò, Ayodeji Rotinwa ni ìròyìnn òfegè gbé àwòrán rẹ̀ síta pè dókítà tó ń pa àwọn Hausa mùsùlùmí

Eto lati yàn  ẹni  tí  yoo gbe asia ẹgbẹ  PDP nibi  idibo gbogbogboo  fun ipo gomina ipinle Oyo yoo  wáyé  láàárín  Gómìnà  Seyi Makinde ati Alhaji Gbolarunmi Hazeem ẹni ti o ti jẹ igbá-kejì  gómìnà  ipinlẹ Oyo nigba kan ri.

Alukoro ẹgbẹ naa ni ipinlẹ  Ọ̀yọ́ Akeem Olagunji fìdí rẹ mulẹ  pe ẹgbẹrun o le aadọta ní  àwọn aṣojú  ẹgbẹ  tí  yoo  di ibo làti  yàn  asoju ẹgbẹ fun ipo gomina ipinle Ọ̀yọ́  ninu egbe PDP.

Hazeem gbolarumi  ni igbákejì  gómìnà  ipinlẹ Ọ̀yọ́  nígbà tí  otunba Adebayo  Alao-Akala  jẹ  gómìnà  ipinle  Ọ̀yọ́ 2017 -2011.

Òun  lo darí  awọn  alatilẹyin  ẹgbẹ  PDP lati yan Rashidi Ladoja gẹgẹ bi gomina  ipinle Ọ̀yọ́ ni ọdun 2006.

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Yatọ si oṣelu o je agbẹjọro.

Ojo kokanlelọgbọn (31) Osu kẹta lo fi erongba  rẹ hàn  lati díje  du ipo gómìnà  ipinlẹ  Ọ̀yọ́.