Àrùn Covid-19 padà bú jáde ní Naijiria, àjọ NCDC àti WHO fi ìkìlọ̀ léde

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Cross River ti ṣawari eeyan kan to lugbadi arun Covid-19.
Ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ ọhun sọ pe oun ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣawari gbogbo awọn to farakan ọmọ orilẹede China to ni arun naa lara lati ya wọn sọtọ fun ayẹwo ati itọju.
Nigba to n ba awọn akọroyin, kọmiṣọna eto ilera ipinlẹ ọhun, Henry Ayuk, fidi rẹ mulẹ pe lootọ arun Covid-19 ti pada sipinlẹ naa amọ awọn ko kawọ gbera lori rẹ.
Ayuk ni igba akọkọ ree ti wọn yoo ri arun naa nipinlẹ ọhun lati ọdun 2022 amọ awọn yoo ri daju pe ko ni tan kanlẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọmọ orilẹede China to ni arun naa wọ Naijiria lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2026 yii.
O sọ pe inu Naijiria lo ti ni arun naa lẹyin ti ọjọ mẹrinla ti arun ọhun maa n lo ko to Farahan ti kọja.
O tẹsiwaju pe ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin ti a wa yii ni apẹrẹ arun naa to bẹrẹ si n farahan lara rẹ.
Kọmisọna ọhun fi kun pe awọn akọṣẹmọṣẹ eto ilera ti lọ si ijọba ibilẹ Akamkpa nibi ti ọkunrin naa n gbe to si ti n ṣiṣẹ lati ri pe arun naa ko tan kalẹ nibẹ.
Ẹnikan lo ni arun naa, ko tii tan kalẹ - NCDC
Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria ti sọ pe lootọ ni ẹnikan ni arun naa nipinlẹ Cross River.
Ninu atẹjade to fi soju opo X rẹ, NCDC sọ pe ẹnikan ṣoṣọ naa to jẹ ọmọ orilẹede China nikan lo ṣi ni arun ọhun, awọn si ti bẹrẹ iṣẹ lati ri pe ko tan kalẹ.
NCDC sọ pe ko tii si ẹri pe arun naa ti tan kalẹ lọwọ yii ṣugbọn oju ni alakan fi n ṣọri.
WHO kilọ fun awọn ọmọ Naijiria ki wọn maa ṣọra
Ẹwẹ, adari ajọ WHO nipinlẹ Cross River, Yewande Olatunde, ti ke si awọn ọmọ Naijiria ki wọn maa ṣọra latari pe arun Covid-19 ko tii tan nilẹ patapata.
Ti ẹ ko ba gbagbe, nnkan bii ẹgbẹrun mẹta eeyan ni Covid-19 mu ẹmi wọn lọ ni Naijiria gẹgẹ bii akọsilẹ ajọ NCDC.
Ipari ọdun 2019 ni arun Covid-19 kọkọ bu jade ni China ko to tan de awọn orilẹede mii kaakiri agbaye, eyii to mu awọn orilẹede kede ofin konile-o-gbele.
Ikede igbele yii ṣakoba fun ọpọ ọrọ aje awọn orilẹede kaakiri agbaye.


























