Kidnapping in Kwara: Gómìnà Kwara kó ṣọ́jà wọ ibùba àwọn ajínigbé l‘Ekiti, Oke-Ero

Oríṣun àwòrán, kwara state government

Gẹgẹ bi ara ọna ati dẹkun eto abo to mẹhẹ ati ọwọja ijinigbepawo ni ipinlẹ Kwara, ijọba ipinlẹ naa ti ko awọn ọmọ ogun wọ awọn ibuba ajinigbe kaakiri agbegbe ijọba ibilẹ Ekiti ati Oke Ero ni ipinlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi awọn iroyin abẹle to n jade ni ipinlẹ naa ṣe sọ, ọpọ awọn iṣẹlẹ ijinigbepawo lo n waye lagbegbe naa nitori awọn ajinigbepawo ti sọ ara wọn di ẹrujẹjẹ nibẹ, tara ile ko lee roko, ti ero ọna ko si lee wale mọ.

Oríṣun àwòrán, kwara state government

Ijọba ipinlẹ ipinlẹ Kwara ni gbogbo ipa lawọn yoo sa, lati rii pe eto abo to mẹhẹ, paapaa julọ ọwọja ijinigbepawo jẹ rodo lọ mumi nibẹ.

Oríṣun àwòrán, kwara state government

O ni eyi yoo seese nipa fifi ọwọ sowọpọ pẹlawọn ajọ alaabo gbogbo to ba yẹ, lati le gbogbo iwa to ba n tigi bọ oju alaafia ipinlẹ Kwara atawọn eeyan rẹ lugbẹ.

Oríṣun àwòrán, kwara state government

Oríṣun àwòrán, kwara state government

Oríṣun àwòrán, kwara state government

Oríṣun àwòrán, kwara state government

Oríṣun àwòrán, kwara state government