Nigeria swearing-in 2019: Wo àwòrán tó jẹ ojú ní gbèsè nípa ìbúra ààrẹ àtàwọn gómìnà

Àkọlé àwòrán, Gele mi ga ju tiẹ lọ lawọn obinrin fi ibura se ni Naijiria

E wo akojọpọ awọn iroyin to lamilaaka nipa ibura awọn gomina ati aarẹ:

Olu-ilu Naijiria, Abuja:

Àkọlé àwòrán, Igba ọtun wọle de, ọmọ Naijiria, Aarẹ Muhammadu Buhari lo sọ bẹẹ bo se n bẹrẹ saa keji pẹlu iburawọle

Oríṣun àwòrán, VON

Àkọlé àwòrán, Igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo naa se ibura
Àkọlé àwòrán, Oye naa tun ko sile wa lẹẹkeji. Orin yii ni awọn eeyan n kọ bi Buhari se n kọja lọ
Àkọlé àwòrán, Bi a ko ba gbagbe ọrọ ana, a kii ri ẹnikan a ba ṣere.

Ipinlẹ Eko:

Àkọlé àwòrán, Gomina sanwo-olu ti ipinlẹ Eko ati ẹbi rẹ.
Àkọlé àwòrán, Awọn ara Eko pejọ si ibi iburawọle fun Gomina tuntun ati igbakeji rẹ.
Àkọlé àwòrán, Igbakeji gomina tuntun ni ipinlẹ Eko ati mọlẹbi rẹ.
Àkọlé àwòrán, Ọwọ ẹrọ ni ibura gomina mu dani ni Eko, Ojo wẹliwẹli rọ le gomina Sanwo-Olu lori
Àkọlé àwòrán, Sokoto penpe ọlọpaa, a fi bii igba ti Naijiria ko i tii gba ominira
Àkọlé àwòrán, Olori eto ẹsọ alaabo ni ipinlẹ Eko di ihamọ ogun wọ.

Ipinlẹ Oyo

Àkọlé àwòrán, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ati igbakeji rẹ, Rauf Olaniyan ti bura wọle gege bii gomina ati igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ
Àkọlé àwòrán, Gomina tuntun naa nipinlẹ Oyo ni oun ni imọ rere fun awọn ara ilu
Àkọlé àwòrán, Igbakeji gomina Oyo, Rauf Aderẹmi Ọlaniyan ree to n se ibura niduro pẹlu aya ati ọmọbinrin rẹ
Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ olorin ni ipinlẹ Ọyọ fi ijo ati ayẹ̀yẹ pada gomina tuntun ni ipinlẹ naa.
Àkọlé àwòrán, Awọn ara ipinlẹ Oyo naa tu yaya tu yaya si gbagede ibi ti wọn ti se iburawọle fun gomina tuntun naa.

Ipinlẹ Kwara

Àkọlé àwòrán, Awọn ara ilorin naa ko gbẹyin ni ibi iburawọle naa
Àkọlé àwòrán, Igbakeji Gomina tuntun ati iyawo re ni ipinlẹ Kwara
Àkọlé àwòrán, Emir ti ilu Ilorin, Zulu Gambarie naa ko gbẹyin ni ibi iburawọle to waye.
Àkọlé àwòrán, Gomina ipinlẹ Kwara tuntun ati iyawo rẹ wọle.
Àkọlé àwòrán, Aṣọ ń pe aṣọ ránṣẹ́ ni lásìkò ìbúra gómìnà àti ààrẹ

Akojọpọ awọn aworan yii wa lati ile isẹ BBC ati Twitter