Akure Anglican Bursar: Àwọn agbébọn gbé owó sálọ lẹ́yìn tí wọ́n pa akápò ìjọ Anglican

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn agbebọn naa tẹle akapo ijọ naa lati ile ifowopamọ nibi ti o ti lọ gba owo

Awọn agbebọn kan ti yinbọn pa akapo ijọ Anglican lẹkun Akure, Gabriel Abiodun ti wọn si gbe owo ti o lọ gba ni ile ifowopamọ salọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo,Femi Joseph lo fidi ọrọ na mulẹ fun BBC Yoruba.

O ni isẹlẹ naa to waye ladugbo Alagbaka jẹ ajoji si ipinlẹ Ondo.

''O dabi ẹni pe ajoji ni awọn agbebọn to hu iwa yi. Amọ ṣa a ti bẹrẹ iwadi ti ko si ni pẹ ti ọwọ wa yoo fi tẹwọn.''

Ko daju iye owo ti oloogbe naa lọ gba nile ifowopamọ .

Oríṣun àwòrán, Femi Joseph@official

Àkọlé àwòrán, Ajoji ni iru iṣẹlẹ yi jẹ fun wa nipinlẹ Ondo

Alukoro ọlọpaa ni nnkan bi ago mọkanla owurọ ọjọbọ ni awọn gburo iṣẹlẹ naa ti o si ni ki awọn to gbe ọgbẹni Gabriel de ile iwosan, o ti dakẹ.

''Wọn tọ lati ile ifowopamọ lọ si ọfisi rẹ ni.Nibẹ ni wọn ka mọ ti wọn ti yinbọn pa ki wọn to gbe owo salọ''