Tìlù tìfọn ní Ọṣun fi kí Buhari káàbọ̀ l'Óṣogbo

Àkọlé àwòrán, Eyi ni yoo jẹ aṣekagba ipolongo idibo gomina fun ẹgbẹ oṣelu APC

Alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC, Adams Oshiomole ti fọrọ lede wipe mimu itesiwaju ba awọn iṣẹ rere ti ẹgbẹ naa ti fi lọlẹ nipinlẹ Ọṣun da lori ẹni ti yoo gba iṣakoso lọwọ gomina Rauf Arẹgbẹṣọla.

Oshiomole ṣe alaye ọrọ naa nibi asekagba ipolongo idibo ẹgbẹ oselu APC to waye lọjọ iṣẹgun, nilu Oṣogbo .

Adari ẹgbẹ osisẹ tẹlẹri ọhun fi kun ọrọ rẹ wipe ''ipinlẹ Ọṣun nilo ẹni to ni oye kikun ati ọgbọn atinuda nipa eto iṣejọba, yatọ si ẹni ti wọn ṣẹṣẹ n kọ.''

Àkọlé àwòrán, 'Ẹni ti a fa kalẹ yi ko kundun ode owanbẹ. Ko le ma a jo skelewu'

O tẹsiwaju wipe idi ti aare Muhammadu Buhari fi ba wọn peju-pesẹ sibi eto naa kii se fun itẹsiwaju isakoso ẹgbẹ oselu APC nikan, sugbọn lati fi da gbogbo eeyan ipinlẹ Ọṣun loju wipe ise rere ti egbe naa ti bẹrẹ yoo yọri.

O ni anfani ti Gboyega Oyetọla fi tayọ awọn oludije ti o ku ni oye ati iriri rẹ nipa eto iṣejọba.

Oríṣun àwòrán, Empics

Àkọlé àwòrán, Eyi ni yoo jẹ aṣekagba ipolongo idibo gomina fun ẹgbẹ oṣelu APC

Oshiomole tẹsiwaju wipe awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ko nilo gomina to kundun ode owanbẹ, tabi ẹni to fẹran ile ijo.

"Ẹni ti a fa kalẹ yi ko kundun ode owanbẹ. Ko le ma a jo skelewu.''

''Mo ranti wipe lọjọ diẹ sẹyin, wọn pe ipade itagbangba fun ifọrọwanilẹnu wo laarin awọn oludije si ipo gomina ipinlẹ Ọṣun, sugbọn ara ibi kọ lati yọọ ju sibẹ,nitori wipe o ti gba ijo lọ.''

Oríṣun àwòrán, @NajeemFSalaam

Àkọlé àwòrán, Awọn Gomina ẹgbẹ APC naa wa gbaruku ti akẹgbẹ wọn Rauf Aregbesola nibi ipolongo ohun

O rọ awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati jade dibo wọn fun ẹgbẹ oṣelu APC lọjọ kejilelogun oṣu kẹẹsan ọdun yi, ki oṣẹ rere ẹgbẹ naa le tẹsiwaju.Ipolongo eto idibo naa ni aṣejagba iruẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC saaju eto idibo si ipo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ naa.

Àkọlé àwòrán, Ni ipari ipolongo naa wọn gbe asia ẹgbẹ fun Gboyega Oyetọla

Lara awọn eekan to ba wọn peju-lesẹ nibi akanṣe eto naa ni aare Muhammadu Buhari, adari ẹgbẹ oṣelu naa, Bola Ahmed Tinubu, Minisita fun ikansira ẹni, Adebayọ Shittu, minisita fun eto ilera Isaac Adewole, ati bẹẹbẹẹ lọ

Àkọlé àwòrán, Bola Tinubu,Adams Osiomole ati awon eekan ẹgbẹ wa lara awọn to peju sibẹ .
Àkọlé àwòrán, Fadeyi Oloro Aliasi Sukee wa nibẹ

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Osun Decides: Adegoke ni òun kò ni lo kọngilá n
Àkọlé fídíò, 'A máa ń bẹ́ orí ẹni tó bá gbé imọlẹ̀ ọdún ìjẹṣu tó bá ṣubú ni'