Serena Williams: Mọ̀ sínú, mọ̀ síkùn ni ìdí tí mo fi kọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Williams to pada si ni gbabọọlu ẹlẹyin lẹyin ti o bi ọmọbinrin rẹ, fi idi rẹmi nigba to n figagbaga pẹlu Briton Johanna Konta pẹlu ami ayo 6-1 6-0.

Ilumọọka agbabọọlu ẹlẹyin, Serena Williams, ti fi lede pe oun ko ni kopa ninu Idije Ife Ẹyẹ Rogers Cup ti yoo waye ni Canada ni ọsẹ to n bọ.

Serena Williams to jẹ ẹni to gbe igba oroke julo ninu awọn to n gba bọọlu ẹlẹyin sọ pe, oun kò lè sọ idi ti oun ko fi ni kopa ninu idije naa fun ẹlomii rara.

O ni ọdọ oun nikun wa, ko ni hande si ẹnikẹni.

Williams to pada si ni gbabọọlu ẹlẹyin lẹyin ti o bi ọmọbinrin rẹ, fi idi rẹmi nigba to n figagbaga pẹlu Briton Johanna Konta pẹlu ami ayo 6-1 6-0.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Adari eto Idije Ife Ẹyẹ Rogers Cup, Eugene Lapierre, ni ko dun mọ awọn ninu bii Serena Williams se yẹra kuro ninu idije naa, amọ O wi pe ọpọlọpọ awọn ilumọọka agbabọọlu ẹlẹyin ni yoo kopa ninu idije naa ti yoo bẹrẹ ni ọsẹ to n bo ni Canada.

Àkọlé fídíò, Ọdunlade Adekọla gbóṣùbà fáwọn ọkùnrin tó ń ran ìyàwó wọn lọ́wọ́
Àkọlé fídíò, 'Obìnrin tí kó ba fẹ́ òṣìṣẹ́ Mọ́ṣúárì, ìpinu rẹ̀ mẹ́hẹ'
Àkọlé fídíò, Fẹla Durotoye: ọ̀rọ̀ ìṣọ̀kan Nàìjíríà tó àpérò ọmọ eríwo