Ibadan Refuse: E wo àwòrán bí ìlú Ibadan se di ààtàn nítorí ìdòtí

Akojọpọ aworan lori ọ̀pọ̀ ẹ̀gbin bí òkè tó sọ Ibadan tii se olu ilu ipinlẹ Oyo di ààtàn:

Àkọlé àwòrán, Oriṣiriṣi awọn panti ati ilẹ ti awọn eeyan n da si aarin igboro ilu Ibadan.
Àkọlé àwòrán, Awọn panti yii ti sọ awọn adugbo kan ni ilu ibadan ti o jẹ olu ilu ipinlẹ Ọyọ ti aatan.
Àkọlé àwòrán, Ikọ BBC Yoruba rin kaakiri awọn adugbo bii Ringroad, Mọkọla, Eleyẹlẹ, Iwo Road, Mọnatan ati Iyana Church.
Àkọlé àwòrán, Iriri wa fi idi ọrọ mulẹ pe pupọ ninu awọn adugbo yii ni ko dun un wo nipasẹ awọn panti ti o kun gbogbo opopona.
Àkọlé àwòrán, Obitibiti idọti ti o gba inu igboro kan le ṣe akoba fun ilera awọn ara ilu.
Àkọlé àwòrán, Awọn eniyan parọwa si ijọba lati pesẹ agba ti awọn eeyan le ko ilẹ ati idọti si.
Àkọlé àwòrán, Bakan naa si ni o pọn dandan fun ajọ kolẹkodọti ni ipinlẹ Ọyọ lati ṣe iṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ.
Àkọlé àwòrán, Ijọba fesi pe laipẹ laijina ohun gbogbo yoo yipada lorii imọtoto ilu Ibadan ati ipinlẹ Ọyọ lapapọ.

Akojọpọ aworan yii wa lati ileesẹ BBC