Ẹ̀dá ò láròpin, Super Eagles ṣẹ́só ìyá fún Cameroon

Oríṣun àwòrán, JAVIER SORIANO

Àkọlé àwòrán, Ikọ Super Eagles ti tẹsiwaju lọ abala to kan ninu idije Afcon 2019

Ikọ agbabọọlu Super Eagles Naijiria ti gbewuro soju ikọ Cameroon lati tẹsiwaju ninu idije Afcon 2019.

Goolu mẹta ni Naijiria fi ṣagba Cameroon ninu ifẹsẹwọnsẹ naa to waye ni Alexandria.

Pẹlu esi yi,,ile koko n tagbe ni fun wọn Cameroon ti Naijiria si tẹsiwaju lọ abala to kan ninu idije naa

Àkọlé fídíò, Ẹ wo bí àwọn olólùfẹ́ Super Eagles ṣe tú lọ sí ibùdo
Àkọlé fídíò, Wilfred Ndidi: Mi ò fi dáa yín lójú pé a máà bórí o!

Bi nnkan ti ṣe n lọ re e :

Odion Ighalo lo gba goolu akọkọ wọle ni iṣẹju kọkandinlogun ifẹsẹwọnsẹ naa

Bahoken da goolu kan pada fun Cameroon ni iṣẹju kọkanlelogoji idije naa.

N'jie de lade ni isẹju kẹrinlelogoji fun Cameroon

Ni abala Keji,Odion Ighalo da goolu kan pada ti o fi di 2-2.

Ko pẹ si igba naa ni Ighalo gba bọọlu gba abẹ agbabọọlu Cameroon kan ti Alex Iwobi si gba bọọlu wọ awọn Cameroon.

Ẹni ba jawe olubori ni yoo tẹsiwaju lati pade Egypt tabi South Africa ni abala to kan ninu idije Afcon 2019.

Àkọlé fídíò, 'Bí Nàìjíríà ṣe gbá eyí tó lọ, mi ò lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ti tònìí'
Àkọlé fídíò, Wilfred Ndidi: Mi ò fi dáa yín lójú pé a máà bórí o!