Stevie Wonder di ọmọ orìlẹ̀èdè Ghana
Oríṣun àwòrán, Ghana Ministry of Interior
Gbajumọ akọrin agbaye ni, Stevie Wonder ti di ọmọ orilẹede Ghana.
Aarẹ Nana Akufo fun Stevie Wonder ni iwe aṣẹ atidọmọonilu nibi ayẹyẹ kan to waye ni Jubilee House, ti i ṣe ileeṣẹ aarẹ orilẹede naa.
Stevie Wonder wa lorilẹede Ghana lọwọ yii pẹlu awọn ẹbi rẹ. Bi ọrọ si ti ṣe ri bayii, o fihan pe mọ orilẹede meji , Ghana ati Amẹrika ni Stevie.
Ṣẹṣẹ ni inu agba akọrin naa n dun pẹlu iwe aṣẹ ọmọ onilu ti wọn fun un naa. Ninu ọrọ rẹ, o ni, iyi nla ni orilẹede Ghana fun oun yii ati pe o ṣe atọna fun ifẹ ọkan oun lati ọjọ pipẹ wa lati ko ẹbi oun wa tẹdo si orilẹede naa.
- Akọ̀wé ìjọba Améríkà, Blinken, balẹ̀ sí Ukraine bí Russia ṣe fẹ́ ya wọ ìlú ńlá míì
- Mọ̀ si nípa ọkọ̀ tó ń lo afẹ́fẹ́ gáàsì tí ìjọba kó wọlé láti rọ́pò ọkọ̀ tó ń lo epo bẹntiró
- Àwọn obìnrin fọ́nmú bí Alfa obìnrin, Kafilat Kaola ṣe wọ́ Saheed Shittu lọ sílé ẹjọ lórí ẹ̀sùn àgbèrè àti ríra ọmọ
- Ọwọ́ tẹ 32 awakùsà lọ́nà àìtọ́ l'Oyo
Oríṣun àwòrán, Ghana Ministry of Interior
Lọdun mẹta sẹyin, Stevie Wonder kede erongba rẹ lati wa tẹdo si orilẹede Ghana, lasiko to fi n ṣe ifọrọwerọ kan pẹlu Opray Winfrey. O ni idi erongba oun yii ko se lori gbọnmọgbọnmọ wahala lorilẹede Amẹrika ati lati lee ṣeto ọjọ ọla rere fun awọn arọmọdọmọ oun.
Ni ọdun 2019, ijọba orilẹede Ghana gbe eto kan kalẹ ti wọn pe ni ọdun idapada, ‘Year of Return Initiative’ lati ṣe koriya fun awọn ọmọ Afrika kaakiri agbaye lati wa tẹdo si orilẹede ọhun.
Lati igba naa, o le ni ọgọrun kan awọn ọmọ ilẹ Afrika lagbaye ti wọn ti fun ni iwe aṣẹ ọmọ onilu lorilẹede Ghana. Awọn kan ninu wọn ti wa tẹdo si orilẹede ghana, awọn miran si ti n gunle oniruuru akanṣe iṣẹ lorilẹede naa.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available