You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn dókítà ṣẹ́wélé ìyanṣẹ́lódì, fún ìjọba ní gbèdéke
Ẹgbẹ́ àwọn dókítà ti ilé ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ ti ṣẹ́wélé ìyanṣẹ́lódì àláìní gbèdéke tí ẹgbẹ́ náà gùnlé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun.
Àtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ fi léde náà lẹ́yìn ìpàdé pàjáwìrì tí wọ́n ṣe darí gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti padà sẹ́nu iṣẹ́ wọn bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́jọ òwúrọ̀ ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹrin, ọdún 2026.
Àtẹ̀jáde náà tí ààrẹ ẹgbẹ́ NARD, Mohammad Usman Suleiman buwọ́lù sọ pé ìjọba àpapọ̀ ti ṣèlérí, tí wọ́n sì sọ àrídájú rẹ̀ pé àwọn máa bẹ̀rẹ̀ sí ní san àwọn àjẹmọ́nú tí àwọn ń bèèrè fùn láti oṣù Kẹrin, ọdún 2026.
Ó ní èyí ló mú kí àwọn pinnu láti ṣẹ́eẹ́lé ìyanṣẹ́lódì náà, kí àwọn sì fún ìjọba ní gbèdéke ọjọ́ mọ́kànlélógún láti ṣe àmúṣẹ gbogbo ìlérí tí wọ́n ṣe fún àwọn.
Suleiman ní àwọn máa bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì míì tí ìjọba kò bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nígbà tí ọjọ́ mọ́kànlélógún náà fi máa pé.
Ẹ ó rántí pé oṣù Kìíní ọdún 2026 ni ìjọba ti kọ́kọ́ ṣe ìlérí láti ṣe àmúṣẹ àwọn àjẹmọ́nú náà kí wọ́n tó sún un sí oṣù Kejì.
Àmọ́ títí di àsìkò yìí, ìjọba kò ì tíì ṣàmúṣẹ àwọn ìlérí náà.
Ẹgbẹ́ náà ní àìmú ìlérí náà ṣẹ mú kí wọ́n má ní ìgbàgbọ́ àti ìfọkàntán nínú ìjọba.
Bákan náà ní wọ́n ń bèèrè fún àwọn gbèsè tí ìjọba jẹ àwọn ilé ìwòsàn kan lójúnà àti ṣe kóríyá fáwọn òṣìṣẹ́.
Ìdí táwọn dókítà ilé ìwòsàn ìjọba fí bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódi lónìí rèé
O ṣee ṣe ki o nira fun ọpọ ọmọ Naijiria lati ri itọju to peye gba lawọn ile iwosan ijọba lẹyin ti ẹgbẹ awọn dokita oniṣegun, NARD, bẹrẹ iyanṣẹlodi lonii ọjọ keje oṣu Kẹrin yii.
Iwadii fi han wi pe awọn dokita nile iwosan ijọba ti daṣẹ silẹ fun ọjọ mọkanlelaadọta lati igba ti ijọba Aarẹ Bola Tinubu ti bẹrẹ.
Eyi si jẹ nnkan to n kọ ọpọ eeyan lominu lori iha ti ijọba apapọ kọ si eto ilera.
Idi ti ẹgbẹ awọn dokita fi gunle iyanṣẹlodi pada
Idi akọkọ ti ẹgbẹ awọn dokita fi bẹrẹ iyanṣẹlodi mii lonii ọjọ Iṣẹgun ni igbesẹ ijọba apapọ lati da sisan owo ajẹmọnu tawọn dokita n gba duro.
Ninu atẹjade kan ti igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ awọn dokita, NEC, fi sita ni wọn ti ṣapejuwe igbesẹ ijọba naa gẹgẹ bi eyi to le ṣakoba fun eto ilera.
Igbimọ alaṣẹ NEC naa sọ pe awọn ṣe ijiroro gidi lori ọrọ naa kawọn to kede wi pe iyanṣẹlodi yoo bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun.
Ẹgbẹ awọn dokita NARD n beere lọwọ ijọba lati fagile igbesẹ rẹ lori ayọkuro owo ajẹmọnu awọn dokita lati oṣu Kẹrin yii.
Wọn ni ayọkuro owo ajẹmọnu naa tako ilana sisan owo oṣu fawọn dokita ile iwosan ijọba.
Ẹgbẹ awọn dokita tun beere lọwọ ijọba lati san owo igbega lẹnu iṣẹ ati owo oṣu ti ijọba n jẹ awọn dokita ni kiakia.
Ẹgbẹ NARD ni aisan owo yii ti ṣakoba fawọn ọmọ ẹgbẹ awọn papaa julọ pẹlu bi nnkan ṣe ri lorilẹede Naijiria bayii.
Awọn dokita tun rọ ijọba lati san owo tawọn dokita maa n lo fun idanilẹkọọ lẹnu iṣẹ ati fun idagbasoke awọn dokita ti ọdun 2026 yii.
Bakan naa ni ẹgbẹ NARD tun rọ ijọba lati san owo ajẹmọnu PAT oṣu mọkandinlogun ti ijọba n jẹ awọn dokita.
Ẹgbẹ NARD wa rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lati tẹle aṣẹ ti ẹgbẹ pa lori iyanṣẹlodi to bẹrẹ lonii.
Ti ẹ o ba gbagbe, ọjọ mẹtadinlogun ni awọn dokita fi gunle iyanṣẹlodi lọdun 2023.
Igbayegbadun lẹnu iṣẹ lawọn dokita ja fun nigba naa ti wọn fi gunle iyanṣẹlodi.