You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ tí gbèdéke tí Trump fún Iran lórí 'Strait of Hormuz' bá kọjá?
Ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, Donald Trump ti gbé gbèdéke kalẹ̀, tó sì tún dúnkokò mọ́ Iran láti ọ̀sẹ̀ márùn-ún tí Amẹ́ríkà àti Israel ti ń gbógunti Iran.
Trump ti wá sọ nínú ìkéde tí ó ṣe lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kẹrin pé àwọn ìkọlù tó lágbára ni wọ́n máa ṣe sí Iran báyìí bí wọ́n kò bá ṣí Strait of Hormuz kí epo gba ibẹ̀ kọjá.
"Láàárín wákàtí mẹ́rin, gbogbo àwọn afárá àti ohun àmúṣagbára orílẹ̀ èdè Iran ni a máa dàwó."
Ó ní láti dènà irúfẹ́ ìkọlù yìí, Iran gbọdọ̀ gbà àwọn nǹkan tí òun ń fẹ́, tó fi mọ́ fífi ààyè gba gbígbé epo láì sí ìdàmú gba Strait of Hormuz.
Bí ó ṣe ku wákàtí díẹ̀ kí gbèdéke ìgbà tí Trump fún Iran dà, kò dájú pé Iran ṣetán láti gba àwọn nǹkan tí Trump ń fẹ́.
Wọ́n kọ̀ láti ṣe ìdádúró ogun fún ìgbà díẹ̀, tí wọ́n sì kéde àwọn nǹkan táwọn ń fẹ́ lọ́wọ́ Amẹ́ríkà.
Tí kò bá sí ìfẹnukò láàárín wọn, ó ṣeéṣe kí Trump tún sún gbèdéke tó fún síwájú àmọ́ tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeéṣe kí wọ́n má kà á kún mọ́.
Ó ṣeéṣe kí Iran àtàwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé yòókù pinnu pé pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun tí Amẹ́ríkà ní àtàwọn irinṣẹ́ tó wà ní ìkáwọ́ wọn, pàápàá pẹ̀lú ìdúnkokò tí Amẹ́ríkà ṣe lópin ọ̀sẹ̀ yìí, pé Amẹ́ríkà kò lágbára tó bí wọ́n ṣe ń dúnkokò.
Trump ń tẹmpẹlẹmọ pé àwọn dojú àwọn iléeṣẹ́ ológun Iran bolẹ̀ àti pé ohun kan tí Iran ní báyìí ni dídènà àwọn ọkọ̀ ojú omit ó ń gbépo láti gba Starit of Hormuz kojá.
Lásìkò àpérò Trump pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn náà ló ti kan sáárá sáwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà fún bí wọ́n ṣe ṣèkọlù sáwọn ibùdó nǹkan ìjà ogun Iran, bí wọ́n ṣe nawọ́ gán Ààrẹ Venezuela, Nicolás Maduro ní oṣù Kìíní ọdún àti iṣẹ́ ìdóòlà tí wọ́n ṣe ní òpin ọ̀sẹ̀.
Òun àtàwọn ikọ̀ ààbò rẹ̀ gbóríyìn fún akitiyan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe, tó fi mọ́ ṣíṣe àkóso ọ̀pọ̀ àwọn ọkọ̀ òfurufú àtàwọn ọmọ ogun àti gbígba ìmọ̀ ẹ̀rọ tó le darí ohun sí ibòmíràn.
"A lè yín àdó olóró sí gbogbo wọn àmọ́ agbéṣùmọ̀mí kan ni wọ́n nílo láti ti Starit of Hormuz."
Ohun mìíràn tí Trump le ṣe ni láti mú ìdúnkokò rẹ̀ ṣẹ. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni Trump tẹmpẹlẹmọ pé òun kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀.
Bí Trump ṣe ń sọ pé àwọn èèyàn Iran ṣetán láti farada ìnira tí ìkọlù Amẹ́ríkà ń ní lórí àwọn eèyàn orílẹ̀ èdè náà, ó sọ pé gbogbo àwọn ohun amáyédẹrùn tí wọ́n bá bàjẹ́ báyìí ni wọ́n gbọdọ̀ tún kọ́ padà, tó sì ṣeéṣe kí Amẹ́ríkà kópa nínú àtúnkọ́ náà.
"Ṣé mo fẹ́ ba ohun amáyédẹrùn wọn jẹ́? Rárá, bí a bá lọ lónìí, ó máa gbà wọ́n tó ogún ọdún láti fi ṣàtúnṣe orílẹ̀ èdè wọn padà."
Ó fi kun pé bí òun bá tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdúnkokò òun, o lè gbà wọ́n tó ọgọ́rùn-ún ọdún láti mú àtúnṣe bá orílẹ̀ èdè wọn padà.
Ó tẹ̀síwájú pé pẹ̀lú gbogbo rẹ̀, àwọn ṣì ń dúnàádúrà láti wá ọ̀nà àbáyọ sí fífi òpin sí ogun yìí láì tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdúnkokò náà.
Bákan náà ló ní òun ní èrò èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn ti jọ gbé yẹ̀wò àmọ́ òun kò ní sọ ọ́ síta.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a ó rì í ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lónìí lẹ́yìn tí gbèdéke tí Trump fún Iran bá kọjá.