Ìdí táwọn dókítà ilé ìwòsàn ìjọba fí bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódi lónìí rèé

Ile iwosan ẹkọṣẹ iṣẹgun UCH niluu Ibadan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O ṣee ṣe ki o nira fun ọpọ ọmọ Naijiria lati ri itọju to peye gba lawọn ile iwosan ijọba lẹyin ti ẹgbẹ awọn dokita oniṣegun, NARD, bẹrẹ iyanṣẹlodi lonii ọjọ keje oṣu Kẹrin yii.

Iwadii fi han wi pe awọn dokita nile iwosan ijọba ti daṣẹ silẹ fun ọjọ mọkanlelaadọta lati igba ti ijọba Aarẹ Bola Tinubu ti bẹrẹ.

Eyi si jẹ nnkan to n kọ ọpọ eeyan lominu lori iha ti ijọba apapọ kọ si eto ilera.

Idi ti ẹgbẹ awọn dokita fi gunle iyanṣẹlodi pada

Idi akọkọ ti ẹgbẹ awọn dokita fi bẹrẹ iyanṣẹlodi mii lonii ọjọ Iṣẹgun ni igbesẹ ijọba apapọ lati da sisan owo ajẹmọnu tawọn dokita n gba duro.

Ninu atẹjade kan ti igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ awọn dokita, NEC, fi sita ni wọn ti ṣapejuwe igbesẹ ijọba naa gẹgẹ bi eyi to le ṣakoba fun eto ilera.

Igbimọ alaṣẹ NEC naa sọ pe awọn ṣe ijiroro gidi lori ọrọ naa kawọn to kede wi pe iyanṣẹlodi yoo bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun.

Ẹgbẹ awọn dokita NARD n beere lọwọ ijọba lati fagile igbesẹ rẹ lori ayọkuro owo ajẹmọnu awọn dokita lati oṣu Kẹrin yii.

Wọn ni ayọkuro owo ajẹmọnu naa tako ilana sisan owo oṣu fawọn dokita ile iwosan ijọba.

Ẹgbẹ awọn dokita tun beere lọwọ ijọba lati san owo igbega lẹnu iṣẹ ati owo oṣu ti ijọba n jẹ awọn dokita ni kiakia.

Ẹgbẹ NARD ni aisan owo yii ti ṣakoba fawọn ọmọ ẹgbẹ awọn papaa julọ pẹlu bi nnkan ṣe ri lorilẹede Naijiria bayii.

Awọn dokita tun rọ ijọba lati san owo tawọn dokita maa n lo fun idanilẹkọọ lẹnu iṣẹ ati fun idagbasoke awọn dokita ti ọdun 2026 yii.

Bakan naa ni ẹgbẹ NARD tun rọ ijọba lati san owo ajẹmọnu PAT oṣu mọkandinlogun ti ijọba n jẹ awọn dokita.

Ẹgbẹ NARD wa rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lati tẹle aṣẹ ti ẹgbẹ pa lori iyanṣẹlodi to bẹrẹ lonii.

Ti ẹ o ba gbagbe, ọjọ mẹtadinlogun ni awọn dokita fi gunle iyanṣẹlodi lọdun 2023.

Igbayegbadun lẹnu iṣẹ lawọn dokita ja fun nigba naa ti wọn fi gunle iyanṣẹlodi.