Wọ́n ti ń ka ìbò alága àti kánsẹ́lọ̀ tó wáyé l'Abuja

Bi wọn ṣe n ka esi ibo naa l'Abuja
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Wọn ti bẹrẹ si n ka esi ibo ijọba ibilẹ to waye ni olu ilu Naijiria, FCT, laarọ oni.

Akọroyin BBC to ṣabẹwo si awọn ibi ti wọn ti n dibo jabọ pe pupọ ninu awọn oludibo naa ni ko jade lati dibo.

Ṣaaju eto idibo ọhun ni awọn alaṣẹ ti kọkọ fofin de lilọ bibọ ero ati ọkọ lasiko ti eto idibo naa yoo maa waye.

Ẹwẹ, awọn onimọ nipa oṣelu ti sọ pe yoo ṣoro lati fi esi ibo naa ṣedajọ lori bi eto idibo ọdun 2027 yoo ṣe ri ati bi awọn ọmọ Naijiria ṣe tẹwọgba Aarẹ Bola Tinubu si.

Ètò ìdìbò alága àti kánsẹ́lọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ nílùú Abuja

Arabinrin kan n dibo niluu Abuja

Awọn oludibo ti bẹrẹ sii dibo ninu eto idibo alaga ati kansẹlọ to n waye lonii niluu Abuja.

Ajọ eleto idibo INEC sọ pe ko din miliọnu kan ati aabọ oludibo to gba kaadi idibo wọn ṣaaju eto idibo oni.

Amọ, abẹwo BBC sawọn ibudo idibo kan l'Abuja fi han pe awọn eeyan ko jade to lati dibo.

Ti ẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni Aarẹ Bola Tinubu, ti kepe awọn olugbe olu ilu Naijiria wi pe ki wọn tu yaya jade lati dibo fun ẹni to ba wu wọn.

A gbọ wi pe awọn nnkan elo idibo ko tete de awọn ibudo idibo kan laaarọ oni.

Ojú títì dá páro páro nílùú Abuja torí ètò ìdìbò tó ń wáyé lónìí

Oju titi da niluu Abuja tori eto idibo to n ṣẹlẹ nibẹ

Oju titi da paro paro niluu Abuja latari ofin konle o gbele ti ijọba kede tori eto idibo to n waye lonii ni olu ilu orilẹede Naijiria.

Ṣaaju ni Minisita Abuja, Nyesom Wike, ti fi atẹjade kan sita ni Ọjọbọ ọsẹ yii pe ki awọn olugbe ilu Abuja duro sile lonii ki wọn le kopa ninu eto idibo naa.

Lonii lawọn araalu yoo dibo yan awọn alaga atawọn kansẹlọ tuntun sipo ni ijọba ibilẹ mẹfa to wa l'Abuja.

Gbogbo ọja lo wa ni titi pa tori eto idibo naa.

Wọnyii ni fọto to n ṣafihan bi nnkan ṣe ri niluu Abuja lonii.

Ko si lilọ bibọ ọkọ loju titi niluu Abuja
Awọn ile ti ọkọ wa niwaju wọn
Awọn ile to wa lopopona ati igi niluu Abuja
Iwaju ile itaja da paro paro niluu Abuja

Òní ni ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ FCT yóò wáyé

Obinrin to n dibo nilu Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oni ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji, ọdun 2026 ni eto idibo ẹkun mẹfẹfa to wa niluu Abuja yoo waye.

Awọn araalu yoo dibo ni Abaji, Abuja Municipal, Bwari, Gwagwalada, Kuje, ati Kwali lati yan awọn alaga ibilẹ mẹfa atawọn kansẹlọ mejilelọgọta kaakiri olu ilu Naijiria.

Eto idibo naa ni akọkọ iru rẹ ti yoo waye lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu buwọlu atunṣe ofin eto idibo ti ọdun 2022 lọjọ mẹta sẹyin.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ofin naa sọ pe wọn gbọdọ fi gbogbo esi ibo ranṣẹ si olu ọọfisi ajọ INEC lati ori ayelujara.

Wọn ni eyii yoo fun awọn araalu lanfani lati maa wo bi esi ibo naa ṣe n wọle lori ayelujara ni ibikibi ti wọn ba wa.

Amọ awọn araalu kan ti tako atunṣe ofin ọhun pe magomago le waye lasiko tabi lawọn ibi ti ẹrọ ayelujara ko ti ṣiṣẹ tabi ja fafa.

Wọn ṣo pe awọn oloṣelu yoo lo anfani naa lati ṣe makaruru lori esi ibo ọhun.

Ẹwẹ, ajọ INEC ni o le ni miliọnu kan abọ ọmọ Naijiria to ti gba kaadi eto idibo, PVC, wọn ni FCT.

INEC ni "awọn ti wọn ni kaadi idibo ti wọn si forukọlsilẹ lati dibo nikan ni yoo lanfani lati kopa ninu eto idibo naa."

Eto idibo yii ni yoo jẹ ekeji iru rẹ ti wọn yoo ṣe labẹ alaga ajọ INEC tuntun, Joash Amupitan.

Awọn onimọ nipa oṣelu Naijiria sọ pe eto idibo naa ni yoo sọ bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe lẹnu to ni FCT.

Wọn sọ pe eto idibo ọhun tun le ṣapejuwe bi awọn araalu yoo ṣe tẹwọgba Aarẹ Tinubu ninu igbiyanju rẹ lati de ipo Aarẹ lẹẹkeji lọdun 2027.