Erin kọlu ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Oyo, pa èèyàn kan, ẹlòmíì di àwátì
Oríṣun àwòrán, Patrick van Katwijk/Getty Images
Eeyan kan ti padanu ẹmi rẹ sọwọ ẹranko igbo, ti eeyan mii si tun di awati lẹyin ti erin kọlu agbegbe Innayin, nipinlẹ Oyo.
Ohun ti a ri gbọ ni pe isẹlẹ naa waye ni nnkan bi aago mẹta kọja ọgbọn isẹju ni Ọjọru, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2026 nigba ti awọn araalu ṣadede kẹfin pe erin ti wọ ilu naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede.
O ni awọn agbofinro, pẹlu ajọsepọ awọn fijilante ati awọn ọdẹ inu igbo, ṣaare lọ sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ni kete ti wọn gbọ iroyin naa lati ilu ọhun.
Ayanlade sọ pe "Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo fẹ sọ fun awọn araalu nipa iṣẹlẹ kan to waye ni ọjọ kẹtalelologun, oṣu Kẹrin, ọdun 2026, ti eranko igbo nla, erin, yawọ ilu Innayin, nipinlẹ Oyo.
"Kete ti a gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni a gbera pẹlu awọn fijilante ati awọn ọdẹ inu igbo.
"Nigba ti a de si ilu naa, a ba oku ọkunrin kan, ti orukọ rẹ n jẹ Ibrahim Tijani, ẹni ọdun marundinlaadọta, ti a si ba ọpọ apa lara rẹ."
Olayinka fikun pe awọn ti gbe oku oloogbe lọ ile igbe oku si to wa nile iwosan gbogbo ilu Iwere Ile fun ayẹwo.
O ni araalu mii, Alhaji Muhammadu Bingin, ẹni adọọta ọdun naa di awati lẹyin ti erin kọlu agbegbe ọhun.
Atẹjade ọlọpaa ni "Lasiko iwadii, eeyan mii, ti orukọ rẹ n jẹ Alhaji Muhammadu Bingin, ọkunrin ẹni aadọta ọdun, ni wọn ti n wa kiri lẹyin ẹranko naa kọlu oun naa.
"Igbiyanju n lọ lọwọ lati ṣawari rẹ," atẹjade naa ṣalaye.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti da awọn agbofinro sita pẹlu awọn ọde ati fijilante lati bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni wọn rọ awọn eeyan ilu Innayin ati ilu to yika pe ki wọn ma foya, ṣugbọn ki wọn yago fun agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye, ki wọn si kesi ileeṣẹ ọlọpaa kete ti wọn ba ṣawari ẹranko ọhun.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available