Tí àtọ̀ ọkùnrin kò bá lágbára tó, àwọn ìṣòro tó lè dá sílẹ̀ fún obìnrin rèé
Njẹ o mọ pe bi atọ ọkunrin ba ṣe dara si ni yoo sọ bi oyun yoo ṣe ri lara iyawo rẹ?
Iwadii ijinlẹ sayẹnsi ti fi han pe atọ ọkunrin ti ko ba dara to le ṣokunfa ki oyun ma tete duro lara iyawo irufẹ ọkunrin bẹẹ.
Nigba mii ti oyun ba duro lara irufẹ obinrin bẹẹ, atọ ti ko lagbara to le fa ki oyun maa walẹ lara irufẹ obinrin ọhun.
Nigba mii ẹwẹ, atọ ti ko ba lagbara le jẹ ki irufẹ ọmọ ti wọn ba fi irufẹ atọ bẹẹ bi ni ọpọlọ ti ko jafafa to bii ti awọn akẹgbẹ rẹ.
Awọn ohun to yẹ ki o mọ too ba fẹ ki atọ rẹ ji pepe
Awọn onimọ ti gba awọn to n mu ọti ati siga mimu lamọran ki wọn ṣe adinku rẹ.
Fun awọn ti kii kii mu siga ati ọti, wọn ni ki wọn din ara sisan asanju ku, ki wọn si maa ṣe ere idaraya loorekoore.
Bakan naa ni wọn ni ki eeyan maa jẹ awọn ounjẹ aṣaraloore ki wọn si jina si awọn aisan ti eeyan le ko lati ara ibalopọ.
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ.



