Afurasí darandaran ṣá Olóyè ìlú Ibadan pa, ṣèlérí láti padà wá fún ìkọlù míì

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lẹyin nnkan bii ọsẹ mẹfa ti awọn agbebọn ṣọṣẹ ni Ori Apata, to wa ni ijọba ibilẹ Ido, nipinlẹ Oyo, iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe wọn tun ti gbẹmi oloye kan nipinlẹ naa.

A gbọ pe Aba Asa, to wa lagbegbe Omi Adio, niluu Ibadan ni wọn ti gbẹmi oloye ọhun to jẹ agbẹ.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe inu oko ni Oloye Mutairu Oladosu, to jẹ Otun Balogun Okelade Okin wa ki awọn afurasi Fulani darandaran to gbẹmi rẹ sibẹ.

Iyawo oloogbe naa ati ọmọ rẹ obinrin ti wọn wa nibẹ lasiko ikọlu ọhun ṣalaye pe awọn ri awọn Fulani meji ti wọn n da ẹran jẹko lori ilẹ baba awọn.

Lẹyin naa ni Oladosu kilọ fun wọn ki wọn kuro lori oko oun.

Asiko to n ni itakurọsọ pẹlu awọn darandaran naa ni awọn darandaran meji mii jade lati inu igbo ti wọn si bẹrẹ si n fi oogun ati ada le iyawo ati ọmọ rẹ obinrin naa ti ọjọ ori rẹ ko tii pe ogun ọdun.

Iyawo ati ọmọbinrin oloogbe naa sọ pe ori lo ko awọn yọ ti wọn to lugọ sinu igbo kan.

Lẹyin ti awọn darandan naa ri pe awọn ti moribọ lọwọ wọn ni wọn pada lọ kọlu Oloye Oladosu ti wọn si ṣa lada pa.

Iyawo oloogbe ọhun ni inu igbo ti oun wa loun ti n wo bi wọn ṣe n ṣa ọkọ oun ti ko si si ohun nnkankan ti oun le ṣe nipa rẹ.

Obinrin naa to ti di opo bayii sọ pe oun ko le pariwo ki awọn darandaran naa ma baa ṣa oun ati ọmọ oun pa.

O ni lẹyin ti wọn gbẹmi ọkunrin naa tan ni wọn na papa bora ki awọn eeyan abule ọhun to de ibẹ.

Awọn eeyan abule ọnaa ni ọlọpaa ti mu awọn afurasi ọhun bayii amọ awọn ko ni igbagbọ ninu ileeṣẹ ọlọpaa lati ri idajọ ododo gba.

Ọkan lara awọn agbagba abule naa sọ fun awọn akọroyin pe awọn darandaran ọhun ti ṣeleri lati pada lọ ṣọṣẹ nibẹ, eyii to mu ki wọn maa rawọ ẹbẹ si ijọba fun iranlọwọ.