Wo àwọn ilé tí ìjọba Eko kò fún láǹfàní láti lo iná 'Solar' láì gbàṣẹ àti ìgbésẹ̀ tó yẹ kí o gbé kí o tó ṣe é sílé rẹ
Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu
Idakureku ina ọba ti kari lorilẹede Naijiria, ọpọ igba ni ina mọnamọna ki I si, eyi to n ṣakoba fun ọrọ aje ọpọ eeyan ati igbesi aye lapapọ gan-an.
Ai si ina deede ọhun lo fa a ti ọpọ eeyan fi n yi si ilana ina to n lo itansan oorun ti a mọ si Solar.
Ina Solar yii ti pọ kaakiri to bẹẹ ti wọn n lo o ni awọn igberiko kiri, ti ọpọ eeyan ko si duro de ina mọnamọna mọ.
Ṣugbọn laipẹ yii ni fidio kan jade lori ayelujara, nibi ti ọkunrin kan to so ina solar mọ ile ijọba Eko to gba, atawọn oṣiṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ile gbigbe nipinlẹ Eko ti n ba ara wọn fa ọrọ kan.
Awọn oṣiṣẹ ijọba naa sọ pe ko ni ẹtọ lati so solar mọle ijọba lai gba aṣẹ nibi to yẹ.
Wọn fi kun un pe o tun ni owo to yẹ ko san pẹlu, ẹnikan ki i deede so solar mọle ijọba lai ṣe awọn nnkan wọnyi.
Bẹẹ ni ọrọ naa di ohun ti wọn n fa mọra wọn lọwọ, ti ọpo araalu si sọ pe ko yẹ ki ijọba di ẹni to ba nilo ina Solar lọwọ, nitori aipese ina ọba lo mu araalu yiju si solar lilo.
Alaye ijọba Eko lori ile to le so ina solar mọle ati eyi ti ofin ko fi aaye gba
Nigba to n ṣalaye lori ọrọ ẹni to so solar mọle ijọba ipinlẹ Eko lai gba aṣẹ, oludamọran pataki lori eto iroyin fun Gomina Babajide Sanwo-Olu, iyẹn Wale Ajetunmobi, sọ pe ọkunrin to ṣe solar sile ijọba Eko naa ko gbọ ofin to de ile to n gbe ye rara ni.
Ajetunmobi ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọruu, sọ pe:
"Ootọ ni igbesẹ yii, ọkunrin to gbe fidio jade naa ko gbọ ofin to de ile ijọba Eko ye, abi ko jẹ pe ayalegbe ni ninu awọn ẹseeti ijọba .
"Nitori ti ko ba jẹ bẹẹ, ko ni I maa ja lori ohun ti ofin ti la kalẹ.
"Ki I ṣe gbogbo ile to wa l'Ekoo ni ko le lo ina solar, ijọba ko si sọ pe oun fẹ gba owo siso solar mọle lọwọ wọn.
"Awọn ile to jẹ tijọba ipinlẹ Eko nikan tawọn eeyan n gbe la maa n sọ pe ki wọn san owo fun ohun ti ko si ninu ile naa ti wọn ṣe sibẹ funra wọn, bii iru solar ti a n sọ bayii, ko too di pe wọn yoo ni anfaani lati gbe igbesẹ rẹ."
Ajetunmobi tẹsiwaju pe awọn nnkan ti ko si nile ijọba ti awon eeyan ba ṣe sibẹ bi eyi gbọdọ gba ofiisi awọn to n ṣe eto ile gbigbe ati aato ilu kọja (Physical Planning and Survey Departments), nileesẹ to n ri si ọrọ ile gbigbe l'Ekoo.
Aṣoju ijoba Eko naa sọ pe ijọba ti koju wahala latari awon nnkan bayii ri, nigba ti ina ṣẹyọ nile ijọba ti wọn fi Solar si.
Ni kukuru, ijọba Eko sọ pe ile gbigbe to jẹ ti araalu le ṣe ina solar lai sanwo fun ijọba tabi gba aṣẹ, ṣugbọn fun awọn eeyan to ba n gbe ni esteeti ijọba Eko, dandan ni ki won gba aṣẹ ṣaaju, ki won si sanwo tijọba la kalẹ ki won too le so solar mole ijọba.
Ki ni ohun to yẹ ki o ṣe ṣaaju lati dena ijamba ina solar?
Bi ina Solar sẹ jẹ ọna abayọ kuro ninu okunkun birimu to si wulo fun ọrọ aje naa lo ni awon ewu to rọ mọ ọn.
Ina maa n ṣẹyọ nigba mi-in, ti odidi ile yoo jo kanlẹ latari solar lilo. Eyi maa n waye nigba ti awọn eeyan ko ṣe ohun to yẹ ṣaaju siso ina solar mọle.
- Wọnyi ni awọn igbesẹ akọkọ to yẹ ki o gbe ki o too so Solar
- Wo ipo ri orule ile tabi ti ọfiisi rẹ ti o fẹ so ona naa mo wa.
Oriṣiriṣi orule lo wa, awọn kan wa ti wọn ko ni alopẹ, won ko ṣee kanju so ina solar mọ, iru awọn wonyi gba ọgbọn ki o too so solar mọ wọn.
- Tun wo apa ibi ti wọn da oju orule rẹ kọ , wo iru nnkan eelo ti won fi se orule naa pẹlu ki o too so solar mọ on.
- inawo ọtọọtọ lo rọ mo siso awon ina solar mọ orule, to si yẹ ki onile boju wo ko too bẹrẹ.
- Apa ibi ti ile rẹ wa"
Bi oorun ba ṣe n tan si apa ọdọ rẹ si ni yoo so iye ina solar ti o nilo lori orule, ati iru eyi ti o gbọdó lo, ati bi waa ṣe gbadun ina naa to.
Ohun to tun ṣe koko lati mọ ni pe bi awon ile giga ba pọ ni agbegbe rẹ, won yoo maa di itansan oorun lowọ, o ko si ni i le gbadun ina naa bo ṣe yẹ.
Bakan naa ni ko o ri I daju pe igi giga ko si nitosi ibi ti o fẹẹ ṣe solar rẹ si, ko maa baa maa di oorun lọwọ.
- Iye owo ti yoo na ọ.
Owo ti won fi n sẹ solar ko kere, o si tun ni I ṣe pẹlu iru eyi to o ba fẹẹ sẹ gan-an.
O ni lati ro bi agbara rẹ ba ṣe to ki o too dagba le solar ṣiṣẹ sile tabi ọfiisi rẹ.
Yan ileeṣẹ to dangajia to si ni aṣẹ ijọba lati ba ọ ṣe solar rẹ.
Eyi yoo fun ọ ni anfaani lati lo o nirọrun, wón yoo si le ba ọ wo o to ba nilo ayẹwo kankan.
- Iye ina ti o nilo fun ile tabi ọfoosi rẹ.
Bo ṣe jẹ pe iye ina ti kalulu nilo yatọ sira wọn lo ṣe jẹ pataki lati mọ iru panẹẹli solar ti o nilo lati ra, o nilo lati mọ iye to maa to ọ ati eyi ti yoo pọju bi o ba kowo le e .
- Iwe aṣẹ gbigba
Ri I daju pe o gba iwe aṣẹ lori ile ti o n sẹ solar ṣi, ko ma baa di ẹjọ mọ ọn lọwọ.
Ewu to rọ̀ mọ́ lilo ina Solar
Ile jijo lati ara ai ṣe solar naa lọna to yẹ.
Ki ina gbe eeyan latari ai bojuto awon waya to yẹ lasiko ti a n lo solar.
Bi ijamba ba kan orule ti a so solar mọ, tabi ti wọn ko ba to o si ori orule naa daadaa lasiko ti wọn n ṣe e, o le pada mu ijamba lọwọ.
Bi a ṣe n tọju batiri ti a fi n rọpo ina solar le fa ki eeyan fa kẹmika buruku simu, bi a ko ba tọju rẹ bo ṣe yẹ.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available