Sokoto Canoe Mishap: Baálẹ̀ abúlé pàdánù ọmọ 5 sínú ìjàmbá ọkọ̀ oju omi tó mú ẹ̀mí 28 lọ
Oríṣun àwòrán, Reuters
Kò dín ní ènìyàn méjìdínlọ́gbọ̀n tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá ọkọ̀ oju omi ní ìlú Gidan-Magana, ìjọba ìbílẹ̀ Shagari, ìpínlẹ̀ Sokoto.
Baálẹ̀ ìlú Gidan-Magana, Mohammed Auwalu ní lọ́jọ́rú, ọjọ́ kẹtàlá, oṣù kẹrin, ọdún 2022 ni ọkọ̀ ojú omi náà rì nígbà tó ń gbèrò láti sọdá sí ìlú òdìkejì tó ń jẹ́ Badiyawa.
Auwalu ní ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi náà wáyé nígbà tí ọkọ̀ ọ̀hún forí sọ igi kan nínú omi tó sì dànù.
- Seyi Makinde ti sọ Auxillary di nǹkan míì sígbòrò, ọlọ́pàá gbọdọ̀ mu - Olopoeyan
- Wo ẹ̀rọ ìgbàlódé tí o lé rì sínú ọwọ́ rẹ̀ láti má a san owó ọ̀jà láì lo káàdì ATM
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ Aláàfin, ẹni tó pààrọ̀ nǹkan obìnrin sí ti ọkùnrin
- Ìkọlù sí Ukraine kò ní dópin àyàfi tó bá ṣe ohun tí mo fẹ́ - Putin
- A rí àwọn fọ́tò tó fihàn pé ọkọ Osinachi ní ìyàwó míràn sí ìkọ̀kọ̀ - Mínísítà fọ́rọ̀ obìnrin
- Ọwọ́ àwọn ológun kò mọ́ lórí ìkọlù agbébọn ní Nàìjíríà - Àwọn aṣòfin àpapọ̀ fọnmú
- Àṣírí ayédèrú ológun méjìlá tó ń gbégi dínà ní Ajah ati agbègbè míì tú sọ́wọ́ iléeṣẹ́ ológun
- Ṣe lóòótọ́ ni pé Osinbajo kìí se ọmọ ẹgbẹ́ APC l‘Eko?
- Èmi ni mo kájúẹ láti di Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà – Tinubu
- Wo ìdí mẹ́ta tí káàdì ìdìbò rẹ̀ kò fi ní wúlò mọ́
- Erin kọlu Amaya Sebastian, àgbà ọ̀jẹ́ ọjọ́gbọ́n nínú isẹ́ ìwádìí kan, ikú ló padà já sí
- Ìwúlò Buhari fún Nàíjíríà tí tán, kò búrú tó bá kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ - Ilana Omo Oodua
- ''Àti ọmọ ọdún mẹ́fà ni mo tí ń fa Cocaine, bí mo ṣe fipá bá Tosin lòpọ̀ rè é, tí mo sì pa á''
Ènìyàn mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ló wà nínú ọkọ̀ náà èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn jẹ́ obìnrin àti ọmọdé.
Ó ṣàlàyé pé ènìyàn mẹ́fà ni wọ́n rí yọ láàyè tó sì jẹ́ wí pé òkú àwọn méjìdínlọ́gbọ̀n yòókù ni wọ́n rí yọ nínú omi náà.
Auwalu ní ọmọ òun márùn-ún ló wà nínú àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà lọ.
Bákan náà ló ṣàlàyé wí pé àwọn ti sin àwọn tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available