Ekiti 2018: Igbákejì Gómìnà ṣèlérí ìtẹ̀síwájú kébi-má-pàlú
Oríṣun àwòrán, @matsecooks
Eto oloogun ebi yoo tẹsiwaju lẹyin iṣejọba Gomina Ayodele Fayose.Oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Ọjọgbọn Kọlapọ Oluṣọla Eleka, lo ṣeleri yii, lasiko ti o n ba awọn oṣiṣẹ kan sọrọ nilu Ado Ekiti.
Eto "oloogun ebi" eleyi ti adape rẹ lede Gẹẹsi jẹ "stomach infrastructure" ni gomina Fayose gbe kalẹ ni ibẹrẹ saa keji iṣejọba rẹ, eyi to si da ọpọlọpọ họwu-họwu silẹ nigba naa.
Iṣọla Eleka to tun jẹ igbakeji ijọba to n kogba wọle lọwọ nipinlẹ Ekiti sọ pe atunṣe ranpẹ yoo ba eto naa eleyi ti yoo gbee kuro ni anfani ipinlẹ nikan lọ si awọn ẹka ijọba ibilẹ gbogbo to wa l'Ekiti.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available
{{rankTranslation}}