Àwọn ǹnkan tó ṣe pàtàkì kí o mọ̀ nípa Dangote Refinery
Oríṣun àwòrán, NIGERIA PRESIDENCY
Oni, ọjọ Aje, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023, ni wọn o ṣe ifilọlẹ ẹbu ti wọn ti n fọ eporọbi(refinery), ti ileeṣẹ Dangote nipinlẹ Eko.
Ẹbu naa to jẹ ti gbajugbaja olokoowo, Aliko Dangote, ni wọn kọ si agbegbe Ibeju-Lekki, ni iroyin ní o tobi julọ nilẹ Africa.
Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn olori orilẹ-ede mii ati èè[kàn ilu ni yoo peju sibi ayẹyẹ naa.
Ireti wa pe àgbá eporọbi to to 650,000 ni wọn o ma a fọ̀ nibẹ lojumọ fun awọn onibaara lati Africa, Asia ati America.
Bakan naa ni awọn kan sọ pe ẹbu naa yoo pese iṣẹ fun eeyan bi ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un.
Ẹbu ifọpo naa ni akọkọ iru rẹ to jẹ ẹbu nla lati ọwọ eeyan kan ṣoṣo.
Àwọn ǹnkan tó ṣe pàtàkì kí o mọ̀ nípa Dangote Refinery
Oríṣun àwòrán, Other
- Agbegbe Ibeju-Lekki ni ẹbu ifọpo naa wa, o si gba to 2,635 eeka ilẹ ti wọn kọ ọ si
- Gẹgẹ bi nnkan ti awọn alaṣẹ ilee\ọ̀ẹ Dangote ṣe sọ, ẹbu ifọpo naa ni iru rẹ, to tobi julọ ni agbaye ti yoo ma a pese odinwọn eporọbi to pọ
- To ba n ṣiṣẹ bo ṣe yẹ, ireti wa pe ibẹ ni wọn o ti ma a fọ gbogbo eporọbi ti Naijiria nilo, ti yoo si tun ni ọpọ yanturu lati tà si ilẹ okeere
- Àgbá eporọbi 177 lo wa ni Dangote refinery, eyi to le gba 4.742 billiọnu lita epo
- Ẹbu ifọpo Dangote ni ibudokọ ori omi tirẹ, lati maa ko awọn ohun elo wọle sibẹ taara, ati kiko eporọbi ti wọn ba fọ̀ jade lọ silẹ okeere
Ẹ fojusọna loju opo yii fun ẹkunrẹrẹ bi ifilọlẹ naa yoo ṣe lọ.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available