COVID-19, Ẹ fọkàn balẹ̀ ìjọba Nàìjíríà kò ni jẹ́ kí Coronavirus tàn kálẹ́ rára- Minisita ìlera

OSAGIE

Oríṣun àwòrán, Others

 Minisita fun Ilera, Dokita Osagie Ehanire ti ṣalaye pe Ijọba apapọ n sa gbogbo agbara rẹ lati dena itankalẹ aarun COVID-19 titun ni orilẹ-ede yii.

 Ehanire sọ eyi ni akoko  ti oun ba awọn akọroyin sọrọ  lori ibiti igbaradi ijọba  de lori itakalẹ ẹya COVID-19  titun.

Minisita salaye pe ile-iṣẹ to risi ilera ti pade pẹlu Ajo  ilera Agbaye ati asoju orilẹ-ede China si Naijiria lati ṣe atunyẹwo awọn iṣẹlẹ titun lori aarun COVID-19 ni Ilu China.

Ehanire sọ pe “itankalẹ aarun COVID-19 ni Orilẹ-ede olominira China pe fun ijiroro laarin Orilẹ-ede yii ati China .

O ni itankalẹ  COVID-19 ni Orilẹ-ede Amerika,China ati yuropu ni akoko otutu yii ko je titun.

 

Minisita fun ilera nii, Orilẹ-ede Naijiria ti gbe igbese akin lati ri wi pe gbogbo ọna abawọle si Orilẹ-ede yii ni o wa ni igbaradi lati kefin aarun COVID-19 laara awọn ti o wọọ Orilẹ-ede yii wa.

Ehanire ro awọn ọmọ orilẹede yii lati gba abere ajesara COVID-19 ati lati lo ibomu nigbati wọn baa wa ni aarin eniyan pupọ.