A kò ní dákẹ́, gbogbo ibi tí àwọn alákatakítí IS bá sá sí ni Somalia, ni a máa lọ - Iléeṣẹ́ ológun

Oríṣun àwòrán, BBC/Amensisa Ifa

Àkọlé àwòrán, Àwọn ológun ń kojú àwọn alákatakítí ẹ̀sìn IS ní Somalia lẹ́yìn tí wọ́n ní ibùdó ní ẹ̀gbẹ́ orí òkè
    • Author, Sahnun Ahmed
    • Role, BBC News Somali
    • Author, Scarlett Barter
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ní àwọn orí òkè ìlú al-Miskad ní orílẹ̀ èdè Somalia, àwọn ọmọ ogun kan kó ara wọn jọ, wọ́n ń wo ikọ̀ alájàngbìlà ẹ̀sìn Islam kan lórí ẹ̀rọ ìléwọ́ kékeré tí wọ́n mú dání.

Èèyàn kan yọ nínú àwòrán náà, tó ń kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò. Ẹni tó mú ẹ̀rọ ìléwọ́ tí wọ́n fi ń wo dúróònù náà dání sọ pé ọkùnrin náà lọ pọn omi fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni.

"Ó ń sáré, tó sì gbé nǹkan pọ̀n sẹ́yìn," ọmọ ogun míì sọ.

Ọkùnrin tó wà nínú àwòrán náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ihò kan, tí àwọn ológun gbàgbọ́ pé ó jẹ́ ibi tí àwọn ikọ̀ alájàngbìlà IS tí iye wọn tó àádọ́ta sí ọgọ́ta ń sá pamọ́ sí.

Iléeṣẹ́ ààbò Puntland ni àwọn ọmọ ogun tó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta tí wọ́n fi sí ibùdó yìí ní ìlà oòrùn àríwá Somalia.

Ní bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, àwọn darandaran ló wà ní ilẹ̀ tí kò sí nǹkankan níbẹ̀ yìí ṣùgbọ́n tí èyí yípadà nígbà tí IS ṣe ìdásílẹ̀ ibùdó wọn sí Africa lẹ́yìn tí wọ́n lé wọn kúrò ní Syria àti Iraq.

Ní oṣù Kẹrin 2025, Ọgágun Michael Langley, tó jẹ́ olórí ọmọ ogun United States Africa Command (Africom) sọ fún ilé aṣòfin Amẹ́ríkà pé láti Somalia ni ISIS ti ń ṣe àkóso àwọn èèyàn wọn káàkiri àgbáyé.

Láìpẹ́ yìí náà ni Amẹ́ríkà ti ń ṣàtìlẹyìn fún Somalia láti gbógunti IS pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń ju àdó olóró sí gbogbo àwọn ibi tí àwọn ikọ̀ alákatakíti ẹ̀sìn náà ń sá pamọ́ sí. Ní 2025, ọgọ́ta ìkọlù ni Pentagon ṣe sí ikọ̀ sí IS ní Somalia.

Oríṣun àwòrán, Puntland Defence Forces

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tricia Bacon, adarí ẹ̀ka tó ń rí sí ètò láti gbógunti ìgbéṣùmọ̀mí ní American University ní Washington DC sọ pé agbára ikọ̀ IS láti ṣe ìkọlù ní abẹ́lé ní Somalia tàbí Puntland ni wọ́n ti mú àdínkù bá.

Àmọ́ ó ní síbẹ̀, IS Somalia ṣì ń ko ipa tó lóòrìn láti ṣe àtìlẹyìn fáwọn ikọ̀ míì ní Africa àtàwọn ibòmíràn bíi Afghanistan.

Ikọ̀ IS Somaliatí wọ́n tí oríkò wọn jẹ́ Puntland ní ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè náà ló jẹ́ ìdásílẹ̀ látọwọ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Somalia kan, Abdulqadir Mumin. Ó ti gbé ní Sweden àti UK, tó sì ní ìwé ọmọ onílùú UK lọ́wọ́.

Ní 2015 ni òun àtàwọn èèyàn mẹ́tàdínlógún míì ṣàfihàn ara wọn nínú fídíò kan. Tí wọ́n ń jẹ́jẹ̀ẹ́ àtìlẹyìn fún IS.

Mumin ti fi ìgbà kàn rí jẹ́ ọmọ ikọ̀ alájàngbìlà al-Shabab, èyí tó ti ń kojú ìjọba láti bíi ogún ọdún sẹ́yìn, tí wọ́n sì ń ṣe àkóso ibi tó pọ̀ bí gúúsù Somalia.

Ikọ̀ IS Somalia ló lé ikọ̀ al-Shabab kúrò ní orí òkè al-Miskad, tí wọ́n sì kó àwọn èèyàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà wọnú ikọ̀ náà, tí wọ́n sì tún di ibi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ikọ̀ IS káàkiri àgbáyé.

Ikọ̀ náà ní ni ipa tó lóòrìn ní ìlú Bosaso tẹ́lẹ̀ rí, tí àbọ̀ ìwádìí Amẹ́ríkà kan lọ́dún 2022 sọ pé IS rí owó tó $2m dọ́là kó jọ lọ́dún 2022 nípasẹ̀ fífi ipá gba owó lọ́wọ́ àwọn olókoòwò abẹ́lé, àwọn oní nǹkan ọ̀sìn, tó fi mọ́ àwọn tó ń kó ọjà wọlé.

Iléeṣẹ́ ológun Puntland gbìyànjú láti lé IS kúrò ní Bosaso ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2025 ṣùgbọ́n ikọ̀ náà ṣì ń ṣàkóso àwọn ìlú kérejé ní ẹ̀gbẹ́ òkè al-Miskad.

Oríṣun àwòrán, BBC/Amensisa Ifa

Àkọlé àwòrán, Mahad Jama ní IS pa ọmọ ẹ̀gbọ́n òun ní ọdún méjì sẹ́yìn

Ọ̀kan lára àwọn ìlú náà ni Dardar, èyí tí àwọn olùgbé rẹ̀ tó ẹgbẹ̀ta (600).

Àwọn olùgbé ìlú náà ní ọ̀pọ̀ àwọn òfin ni àwọn IS gbé kalẹ̀ fún àwọn. Lára rẹ̀ ni pé ọkùnrin àti obìnrin kò gbọdọ̀ máa dàpọ̀ ní ìta gbangba, ọkùnrin kò gbọdọ̀ wọ ṣòkòtò kọjá kókósẹ̀ wọn tàbí gé irun aláràǹbarà sórí. Bákan náà ló ní irú hìjáàbù táwọn obìnrin gbọ́dọ̀ máa wọ̀ pẹ̀lú ìbọ̀wọ́ àti ìbọ̀sẹ̀, tí wọn kò sì tún fi ààyè gba orin kíkọ.

Àwọn òfin líle wọn ń mú ìgbé ayé le koko fún àwọn aráàlú.

"Ayé le gidi láti gbé," Said Mohamud Ibrahim tó jẹ́ Ìmọ́ọ̀mù ní mọ́ṣáláṣí kan sọ. Ó ní ìbẹ̀rù ni àwọn èèyàn fi ń gbé, tí wọ́n sì ń jí ọ̀pọ̀ èèyàn gbé.

Nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sá fi ìlú sílẹ̀, ó dúró ṣùgbọ́n tó ní àwọn IS yọ òun gẹ́gẹ́ bí Ìmọ́ọ̀mù, tí wọ́n sì gba mọ́ṣáláṣí mọ́ òun lọ́wọ́.

Ó ní wọ́n sọ pé tí òun kò bá fi mọ́ṣáláṣí sílẹ̀, òun máa rí ohun tó yẹ òun.

"Mo mọ nǹkan tó túmọ̀ sí, yálà kí wọ́n bẹ́ orí mi tàbí kí ọ́n jí mi gbé."

Lára àwọn olùjọ́sìn ní mọ́ṣáláṣí náà ni Mahad Jama. Ọdún méjì sẹ́yìn ni àwọn jí ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Shukri gbé, wọ́n sì pa ọmọ náà.

Ó ní inú oyún ni Shukri wà nígbà tí wọ́n pa á, tó sì fi ọmọ méjì àti ìyá sáyé

Jama ní mùsùlùmí òdodo ni Shukri nígbà tó wà láyé, tí àwọn kò sì mọ ìdí tí wọ́n fi pa á.

"Shukri ní ọmọ ọdún méje tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Said. Ọmọ náà tó jẹ́ odi wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀ ní alẹ́ tí àwọn IS pa ìyá rẹ̀ tí wọ́n sì pa òun náà."

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù, iléeṣẹ́ ológun Puntland gba akòsó ìlú náà padà ní oṣù Kejì, ọdún 2025. Amẹ́ríkà ṣe ìrànwọ́ nípa pípa ọmọ IS mẹ́ta lóṣù Karùn-ún ọdún 2024.

Oríṣun àwòrán, BBC/Amensisa Ifa

Àkọlé àwòrán, Muna Ali Dahir is one of a handful of women fighting with the Puntland Defence Forces

Síbẹ̀síbẹ̀, IS ṣì ní ibùdó láwọn agbègbè náà.

Ní ibùdó wọn lórí òkè náà, kò sí ìgbà tí ìkọlù pẹ̀lú IS kò lè wáyé, táwọn ohun ìjà sì máa ń wà ní sẹpẹ́.

Muna Ali Dahir, ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin ọmọ ogun tó ń kojú IS ní Somalia. Ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀ ogun.

"A ti jagun líle tí a sì borí nítorí ilẹ̀ wa nìyí.

Ní àsìkò yìí, orí òkè náà ló ń gbé, tí wọ́n sì ń gbáradì fún ohunkóhun tó le ṣẹlẹ̀.

Ní June 2025, UN ní àwọn ọmọ ikọ̀ IS tó wà ní Somalia tó 800 tí ọ̀pọ̀ wọn sì jk ọmọ ilẹ̀ òkèèrè.

Iléeṣẹ́ ológun Puntland sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ológun IS ni àwọn ti pa láti oṣù mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn, tí wọ́n sì fi àwóràn àwọn tó lé ní àádọ́ta ti wọ́n ti mú láti Ethiopia, Morocco àti Syria léde.

Àwọn aláṣẹ Puntland ní àwọn tí ọwọ́ tẹ̀ máa kojú ìgbẹ́jọ́, tó sì ṣeéṣe káwọn míì gba ìdájọ́ ikú.

Àjọ Human Rights Watch ti kọminú lórí bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ní wọ́n kópa nínú IS. Ìjábọ̀ UN kan lọ́dún 2022 sọ pé Somalia ń ri dájú pé wọn kò tẹ ẹ̀tọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà ní àhámọ́ mọ́lẹ̀.

Oríṣun àwòrán, BBC/Amensisa Ifa

Àkọlé àwòrán, Abddikhair Jama sọ pé: "Àwọn kò ní sinmi àfi tí wọ́n bá pa gbogbo IS run"

Abddikhair Jama wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlá nígbà táwọn ikọ̀ alákatakítí ẹ̀sìn IS kọ́kọ́ dé ẹkùn wọn. "Mi ò mọ̀ pé wọ́n wà rárá, mo rò pé ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni àmọ́ nígbà tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wọn, mo gbà pé àwọn ará ìta ti wá ṣèkọlù sí orílẹ̀ èdè wa."

Bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ ni ìró ìbọn ń dún ní gbègbè náà, táwọn ológun sì ń gbáradì láti lọ kojú àwọn ọmọ ogun IS.

Ọ̀gá àwọn ológun ṣàlàyé pé dúróònù ń yí gbogbo ojú òfurufú láti ṣe ìrànwọ́ fún wọn láti mọ ibi tí wọ́n máa ṣèkọlù sí.

Wọ́n tún fi dúróònù míì ránṣẹ́ sí ojú òfurufú láti mọ nípa ọṣẹ́ tí ìkọlù náà ti ṣe tó sì ṣàfihàn pé ihò náà ti là díẹ̀.

Iléeṣẹ́ ológun Puntland padà ṣàwárí rẹ̀ pé dúróònù Amẹ́ríkà náà kún àwọn tó ṣe ìkọlù sínú ihò náà àmọ́ wọn ò lè sọ iye alákatakítí IS tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.

Gbígbé ogun ti IS ní Somalia kò ì tíì dópin.

Tricia Bacon ṣèkìlọ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kán ìyẹ́ àwọn IS Somalia díẹ̀, wọ́n ti fi hàn pé ikọ̀ tó ní ìfaradà tó pọ̀, tí wọ́n sì lè sọ dí padà láìpẹ́.

Abddikhir sọ pé àwọn kò ní kó àárẹ̀ ọkàn títí tí wọn fi máa pa gbogbo àwọn ikọ̀ IS run.

"Kò bá à gbà wá ní ọdún mẹ́wàá tàbí mẹ́ẹ̀dógún, gbogbo ibi tí wọ́n bá lọ tàbí sá pamọ́ sí ni a máa tẹ̀lé wọn. ìgbà tí ilẹ̀ wab á mọ́ la máa sinmi."

Òun àtàwọn ọmọ ogun míì ń gbé níbi tó nira. Kò sí omi tó mọ́ tàbí iná ọba níbẹ̀, tí wọ́n sì ń sùn ní àwọn abẹ́ igi tàbí òkúta.

Àwọn ewúrẹ́ tí wọ́n bá ń pa ni wọ́n ń jẹ [tàwọn oúnjẹ tí wọ́n ń fi ọkọ̀ òfurufú gbé wa fún wọn ní ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀.

Pẹ̀lú gbogbo rẹ̀, Dahir tó ní ọmọ mẹ́jọ pe àwọn ẹbí rẹ̀. Ẹ̀ẹ̀mejì péré ló ti rí wọn láàárín ọdún kan.

Ó ní àwọn ọmọ òun ló ń fún òun ní ìwúrí láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú ogun náà

"Èmi ni m oni orílẹ̀ èdè yìí, kò sí ààyè fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ kógun jà á."